Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ibanujẹ nla lọrọ iku ọkan ninu awọn akẹkọọ ileewe giga Yunifasiti Oye-Ekiti, to wa nipinlẹ Ekiti, Adebọla Oluwatumininu, to waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, jẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ ati olukọ ileewe naa. Akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn pe ni ọmọ Yahoo, lo wa mọto niwakuwa, to si lọọ ya ba ọmọbinrin naa lasiko ti oun atawọn ọrẹ rẹ n lọ ninu ọgba ileewe ọhun.
Ipele kẹta ni ẹka eto ẹkọ nipa imọ ẹrọ ni wọn ni Adebọla wa. Iṣẹlẹ iku akẹkọọ yii fẹẹ da ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye ti wọn n ṣe lọwọ nileewe naa ru. Niṣe ni wọn sare gbe akẹkọọ-binrin naa digba-digba lọ sileewosan ijọba apapọ to wa ni Ido-Ekiti, fun itọju, ṣugbọn o pada jade laye.
A gbọ pe ọpọ akẹkọọ lo mọ ọmọkunrin to wa mọto to pa ọmọbinrin ọhun bii gbaju-gbaja ọmọ Yahoo. Wọn ni niṣe lo kuro ni ọna tirẹ, to si lọọ ya ba ọmọbinrin yii ati awọn ọrẹ rẹ ti wọn n lọ lẹbaa ọna.
Ni kete ti iroyin iku ọmọdebinrin naa de setiigbọ awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ ni wọn bẹrẹ si i bara jẹ, ti inu wọn ko dun si ohun to ṣẹlẹ naa. Niṣe ni wọn dawọ eto ẹkọ duro lẹsẹkẹsẹ, ti Ọjọgbọn Dosu Malọmọ, to n ri si ọrọ awọn akẹkọọ nileewe naa si paṣẹ pe ki wọn fagi le eto ikẹkọọ fun ọjọ meji lati bu ọla fun akẹkọọ to ku ọhun.
O ṣapejuwe iku akẹkọọ ọhun gẹgẹ bii adanu nla fun ileewe naa.
Ninu ọrọ tiẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ọga ọlọpaa to wa niluu Ọyẹ-Ekiti ti fi iṣẹlẹ naa sọwọ si oun. O fi kun un pe ọmọ Yahoo naa ti wa latimọle awọn agbofinro, iwadii si ti n tẹsiwaju lori ọrọ naa.