Monisọla Saka
Oludasilẹ ati alaṣẹ ile ifowopamọ First City Monument Bank, FCMB, Ọtunba Michael Ṣubomi Balogun, ti faye silẹ lẹni ọdun mọkandinlaaadọrun-un (89).
Ileewosan kan niluu London, ni wọn ni baba yii dakẹ si laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lẹyin aisan ranpẹ, bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to mọ ohun to ṣokunfa aarẹ ati iku to pa baba naa.
Ọtunba Ṣubomi to jẹ ọmọ idile ọba Tunwaṣe, niluu Ijẹbu-Ode, jẹ oloye Ọtun Tunwaṣe ilẹ Ijẹbu, olori ọmọ ọba ilẹ Ijẹbu ati Aṣiwaju awọn ọmọlẹyin Kiristi ni gbogbo ilẹ Ijẹbu pata.
Gẹgẹ bi oloye agba nilẹ Ijẹbu, awọn alaṣẹ o ti i kede iku rẹ, ṣugbọn owuyẹ kan sọ pe awọn mọlẹbi ti fi to ọba Awujalẹ ilẹ Ijẹbu leti, ti wọn yoo si kede iku rẹ ni ibamu pẹlu aṣa ati iṣe ilu naa laipẹ.
Ile iwe girama, Igbobi College, Yaba, nipinlẹ Eko, ni oloogbe ti kawe mẹwaa, lẹyin naa lo tatapopo lọ sileewe London School of Economics, nibi to ti kawe gboye.
Lẹyin to kẹkọọ jade tan, o ṣiṣẹ amofin lawọn ileeṣẹ eto ofin ijọba apa Guusu ilẹ Naijiria, ati nileeṣẹ eto idajọ ilẹ Naijiria, ko too di pe o fiṣẹ naa silẹ lẹyin ti wọn ditẹ gbajọba lọdun 1966.
Lẹyin iditẹgbajọba yii ni oloogbe darapọ mọ ileeṣẹ ifowopamọ, lọdun 1979, lo si pada da banki FCMB silẹ.
Nigba aye rẹ, ọkunrin afunni-mawobẹ yii lo kọ ile iwosan itọju awọn ọmọde, National Pediatric Centre, siluu Ijẹbu-Ode, eyi to kọ lorukọ ile iwosan ẹkọṣe Iṣẹgun Fasiti Ilu Ibadan, UCH.