Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni wọn ri oku ọkunrin kan ti wọn ti ge ori ẹ lọ, ti ko si ẹni to da ẹni naa mọ, niwaju ṣọọbu kan ni agbegbe Sakama, l’Opopona Naija, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti wọn si da asọ idọti le e mọlẹ.
Ọkunrin to ni ṣọọbu ọhun to ni ka ma darukọ oun sọ pe ni kete ti oun de ṣọọbu lati maa ba iṣẹ aje oun lọ jẹẹjẹ loun ri awọn aṣọ idọti niwaju ṣọọbu naa, ṣugbọn ero toun ni pe ojo to rọ ni Ọjọruu, Wẹsidee, lo rọ idọti ọhun si iwaju ṣọọbu naa, ṣugbọn bi oun ṣe fẹẹ maa ko idọti ọhun loun ṣakiyesi pe oku ni wọn da awọn aṣọ idọti le mọlẹ ki i ṣe idọti lasan, kọda, wọn ti ge ori ẹ lọ pẹlu.
Ileesẹ ọlọpaa ẹka ti ipinlẹ Kwara ti gbe oku ọkunrin naa lọ, wọn ni iwadii yoo bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.