O ma ṣe o! Wọn gun akẹkọọ LAUTECH pa l’Ogbomọṣọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọfọ kan ti ṣẹ wọn nileewe giga Ladoke Akintọla University of Technology ( LAUTECH), to wa niluu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, bayii, pẹlu bi wọn ṣe gun ọkan ninu awọn akẹkọọ fasiti naa, Adedokun Basit Ọlamilekan, lọbẹ pa.

Ija ti akọroyin wa ko ti i mọdi ẹ bayii, la gbọ pe o waye laarin Ọlamilekan pẹlu awọn kan laduugbo ti wọn n pe ni Under-G, niluu Ogbomọṣọ, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, laarin ọpọlọpọ iṣẹju ni wọn fi n tahun sira wọn, ti ẹnikan ko gba fẹnikan laarin ikọ mejeeji.

Lẹyin ti igbiyanju lati pari ija naa ko seeso rere fawọn eeyan to wa nibẹ lọkan ninu awọn ọkunrin naa gun Ọlamikekan lọbẹ nigbaaya, oju-ẹsẹ lo si ti mẹyin lọ sile.

Ni kete t’ọmọkunrin naa ti ṣubu silẹ to bẹrẹ si i japoro iku lawọn eeyan naa ti sa lọ, ti ẹnikan ko si mọ wọn titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Amọ ṣaa, awọn araadugbo ọhun du ẹmi ẹ pẹlu bi wọn ṣe sare gbe e lọ sileewosan aladaani kan to wa nitosi ibẹ, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi debẹ, ọmọkunrin naa ti dagbere faye.

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to mọ ẹni to huwa ọdaran yii gan-an, awọn kan sọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn eeyan naa.

Tẹ o ba gbagbe, laduugbo ti wọn pa akẹkọọ LAUTECH yii si naa lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ṣoro laipẹ yii, eyi to mu ki ibọn ọkan ninu awọn ọlọpaa ti awọn araadugbo naa pe lati waa daabo bo wọn fi ba ọmọkunrin kan, to si tibẹ gbẹmi-in mi.

Akinkanju ọmọ ni wọn pe oloogbe yii, nitori bo ṣe n lọ sileewe lo tun n ṣiṣẹ baaba laduugbo Under-G, nigboro ilu Ogbomọṣọ.

Leave a Reply