O ma ṣe o, wọn yinbọn pa alaga APC atawọn eeyan rẹpẹtẹ  

Adewale Adeoye

Inu ọfọ nla gbaa ni awọn araalu Oganienugu, nijọba ibilẹ Dekina, nipinlẹ Kogi wa bayii. Eyi ko sẹyin bawọn janduku agbebọn kan ṣe ya bo abule naa lọganjọ oru ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti wọn si pa ọpọ awọn araalu naa danu. Alaga wọọdu APC agbegbe naa, Ọnarebu James Adah, wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.

Ko sẹni to le sọ pato iye awọn eeyan ti wọn padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ aburu yii.

Lori iṣẹlẹ aburu ọhun, Gomina ipinlẹ Kogi, Alhaji Yahaya Bello ti bu ẹnu atẹ lu awon janduku agbebọn ti wọn loọ da alaafia ilu naa laamu. O ni ohun aburu pata gbaa ni wọn ṣe, paapaa ju lọ lasiko aawẹ Ramadan. O fi kun un pe ko seni ti ko mọ pe awọn olugbe agbegbe naa nifẹẹ alaafia nigba gbogbo.

Bello ni ijọba oun ko ni i kaaarẹ ọkan rara lati maa gbogun ti awọn oniṣẹ ibi. Ati pe ki awọn ọlọpaa ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lati fọwọ ofin mu awọn ẹni ibi naa ni kia.

Bakan naa lo ba gbogbo awọn eni ti wọn pa awọn eeyan wọn kẹdun, paapaa ju lọ ti ẹbi alaga wọọdu ẹgbẹ APC to padanu ẹmi rẹ bayii.

Ni ipari ọrọ rẹ, Gomina Yahaya ni ki awọn araalu ni suuru ki wọn fi wa awọn to ṣiṣẹ buruku naa lawaari, ki wọn ma sọ pe awọn feẹ ṣedajọ loo ara awọn.

 

Leave a Reply