Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn ọbayejẹ ẹda ti sọ̀kò ibanujẹ sinu idile Kọmiṣanna fọrọ akanṣe iṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Funmilayọ Oriṣadeyi, pẹlu bi wọn ṣe yinbọn pa aburo rẹ to n jẹ Oriṣadeyi Adedokun.
Ori ọkada l’Adedokun wa ti wọn fi yinbọn fun un, ko si ju ọgbọn iṣẹju lọ sigba naa to ku.
ALAROYE gbọ pe awọn adigunjale to fẹẹ ja ọlọkada to gun lole ni wọn yinbọn pa a nibi ti wọn ti n gba gbiyanju lati ja alupupu naa gba, ṣugbọn ti ọlọkada ọhun n du u mọ wọn lọwọ. Ibọn awọn adigunjale yii ko si ba ọlọkada, Adedokun to jokoo sẹyin alupupu lo lọọ ba.
Ọlọkada to rin kọja sasiko naa ni wọn lo figbe ta ti awọn ẹlẹyinju aanu fi sare gbe e digbadigba lọ sileewosan lati le doola ẹmi ẹ.
Gẹgẹ bi ẹgbọn ọkunrin naa, Ọnarebu Oriṣadeyi, ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, o ni ileewosan meji ọtọọto ni wọn sare gbe Adedokun de, ṣugbọn to jẹ pe bi wọn ṣe n gbe e debẹ ni wọn n kọ ọ. Bi wọn ṣe kuro nileewosan keji loro ibọn mu un, to si ṣe bẹẹ jade laye.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lati le ri awọn ọdaran naa mu ni ibamu pẹlu aṣẹ ti CP Joe Nwachukwu Enwonsu ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ pa fun wọn.