Faith Adebọla
Afi bii ewurẹ ti wọn ni ki i ṣiwọ to ba tẹnu bọ iyọ, bẹẹ lọrọ awọn agbebọn agbegbe ipinlẹ Zamfara ri lasiko yii, wọn lawọn afurasi ọdaran naa tun ji eeyan to ju aadọrin lọ gbe l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.
Lọtẹ yii, abule Ruwan Tofa, nijọba ibilẹ Maru, nipinlẹ naa, ni wọn kọ lu, awọn obinrin to n tọmọ lọwọ atawọn ọmọ wọn keekeeke la gbọ pe wọn ji gbe, wọn si ko gbogbo wọn wọ’gbo lọ.
Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), sọ pe niṣe lawọn agbebọn naa da ibọn bole ni koṣẹkoṣẹ bi wọn ṣe de agbegbe ọhun, eyi si mu kawọn olugbe adugbo naa sa kijokijo pẹlu ibẹru, ni wọn ba bẹrẹ si i gan awọn obinrin atawọn ọmọ wọn lapa.
Ki i ṣawọn eeyan nikan ni wọn lawọn agbebọn naa ji gbe, wọn tun ji awọn dukia wọn, ounjẹ, aṣọ, ati awọn ẹran ọsin wọn lọ. Lẹyin eyin lawọn janduku agbebọn naa sọ ina si ile ati awọn mọto ti wọn ba lagbegbe naa, wọn sun wọn rau.
Ẹnikan to ba NAN sọrọ nipa iṣẹlẹ yii sọ pe ọpọ wakati lawọn to waa ṣakọlu naa fi yinbọn, ki wọn too ko eeyan to ju aadọrin lọ wọnu igbo.
Wọn nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara lawọn ṣi n ṣewadii nipa iṣẹlẹ naa, awọn o ti i le sọ pato nipa ẹ, ṣugbọn awọn yoo sọrọ laipẹ.