Stephen Ajagbe, Ilorin
Iroyin kan to tẹ wa lọwọ sọ pe Alhaji Aminu Logun ti i ṣe olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina ipinlẹ Kwara ti jade laye.
Ileewosan kan niluu Ilọrin ni wọn lọkunrin naa ku si lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Ohun ta a gbọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ arun Korona lo pa a.