Ibrahim Alagunmu Ilọrin
L’Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ibugbamu afẹfẹ gaasi ṣeku pa iyawo ile kan, Arabinrin Adeọla Adewale, ni Tebanacle 2c Area, Garaji Ẹgbẹ, niluu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara, ti ọkọ rẹ, Adewale, si fara pa yanna-yanna.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ panapana ni Kwara, Hassan Akeem Adekunle, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ kọja isẹju marun-un laaarọ ọjọ Aje, ni iṣẹlẹ buruku naa sẹlẹ nigba ti Arabinrin Adeọla fẹẹ dana ounjẹ fun mọlẹbi rẹ ni gaasi naa gbana mọ ọn lọwọ.
Adekunle sọ pe awọn agbegbe ti ina ṣe lọsẹ ni ileedana, yara igbalejo ati ile-ounjẹ, ti wọn si ti gbe ọkọ obinrin naa to fara kaasa nibi iṣẹlẹ yii lọ si ileewosan fun itọju to peye.
Ọga ajọ panapana ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, rọ gbogbo awọn iyawo ile ki wọn lọọ kẹkọọ nipa bi wọn ṣe maa n ṣamulo afẹfẹ gaasi lati fi dana, ki wọn le dena pipadanu ẹmi ati dukia lọwọ afẹfẹ gaasi.