Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina Adegboyega Oyetọla tipinlẹ Ọṣun ti sọ pe yoo nira fun ẹgbẹ oṣelu miiran yatọ si APC lati gbajọba nipinlẹ Ọṣun latari awọn oniruuru idagbasoke to n ṣẹlẹ nipinlẹ naa lọwọlọwọ.
O ni ẹgbẹ APC ko ni i gbe aṣẹ iṣejọba to wa lọwọ wọn silẹ bayii nitori, gẹgẹ bo ṣe n ṣẹlẹ lọwọ nipinlẹ Eko, awọn yoo ri i pe ko si ẹgbẹ miiran ni ẹka kankan kaakiri ipinlẹ naa yatọ si ẹgbẹ APC.
Nibi ipolongo ibo fun saa keji rẹ, eleyii to waye niluu Ila, ni gomina ti sọ pe pelu oore-ofe Ọlọrun, oun yoo lo saa meji oun pe perepere.
O rọ awọn araalu lati gba kaadi idibo wọn, nitori eleyii ni yoo fun wọn lanfaani lati dibo fun egbe oselu APC. Oyetọla sọ siwaju pe pupọ nnkan to n bi awọn araalu ninu lọdun mẹrin sẹyin ni atunṣe ti de ba, ara si ti n tu wọn bayii.
Ṣugbọn nigba to n fesi si ọrọ ti gomina sọ yii, Alakooso eto iroyin fun ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ọṣun, Ọladele Oluwabamiji, sọ pe ọrọ ti gomina sọ naa le da wahala silẹ laarin ilu.
O ni o tumọ si pe gomina ti fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lagbara lati ṣakọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ PDP, ki ẹgbẹ wọn ba a le wa lori aleefa titi.
O ni awọn araalu ni wọn yoo sọ gomina ti wọn fẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.