O n rugbo bọ o! Igbimọ to n gbọ ẹsun ibo aarẹ gba awọn iwe-ẹri Tinubu ti ẹgbẹ PDP ko kalẹ gẹgẹ bii ẹri

Faith Adebọla

Ẹkọ ko ṣoju mimu fun ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije wọn, Aarẹ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), niwaju igbimọ to n gbọ awọn ẹsun to su yọ lasiko idibo to kọja yii pẹlu bi adajọ ile-ejọ giga naa ṣe da ẹbẹ ti wọn n bẹ kootu ọhun pe ko ma gba awọn iwe-ẹri ileewe ti Aṣiwaju Tinubu loun lọ niluu oyinbo ati awọn ileeṣẹ to ni oun ti ṣiṣẹ, eyi ti ẹgbẹ PDP ko kalẹ ti wọn ni ayederu ni wọle gẹgẹ bii ẹri.

 Ni bayii, adajọ ti gba gbogbo awọn iwe-ẹri naa wọle, ninu eyi ti ileewe fasiti to ni oun lọ niluu oyinbo, iwe-ẹri to loun gba lasiko to fi n sin ijọba gẹgẹ bii agunbanirọ ati eyi to ni wọn fun oun lasiko ti oun n ṣiṣẹ nileeṣẹ Mobil wa.

Ọkan ninu awọn ẹlẹrii to mu iwe ọhun wa lẹyin ti ẹni kan lati ilu oyinbo ti duro fun wọn lati gba awọn iwe naa lorukọ won, to si ni ontẹ ijọba lori, Mike Enahoro Ebah, ko awọn iwe ọhun kalẹ, eyi to fi han pe Bọla Adekunle Tinubu lo wa ninu iwe-ẹri ti Tinubu gba, to si pe ni tiẹ yii. Ati pe orukọ obinrin lo wa lori ọkan ninu awọn iwe-ẹri ọhun.

Lasiko ti igbẹjọ ọhun n lọ lọwọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa yii, ni awọn agbẹjọro oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, eyi ti Chris Uche (SAN), lewaju ti ko awọn iwe-ẹri naa kalẹ, eyi to ṣafihan orukọ ọtọọtọ ninu awọn iwe-ẹri ọhun ati eyi ti Tinubu ko kalẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa nigba to fẹẹ dije dupo aarẹ. Bakan naa ni awọn agbẹjọro Atiku yii tun mu fọọmu ti wọn n pe ni ati EC9 ti Tinubu fi gba fọọmu lati dije dupo wa si kootu.

Yatọ fun eyi, ẹlẹrii Atiku tun mu awọn esi idanwo lati ileewe ti Tinubu loun lọ, iyẹn South West College, eyi ti wọn fi ranṣẹ si Yunifasiti Chicago, iyẹn yunifasiti ti Bọla Tinubu loun lọ, ṣugbọn to jẹ pe orukọ obinrin lo wa lori esi idanwo naa.

Bakan naa ni wọn tun mu iwe idajọ kan to fi han pe Tinubu gba lati yọnda awọn dukia rẹ kan nitori awọn iwa ọdaran kan ti wọn ka mọ ọn lọwọ. Lara ohun ti wọn tun mu wa siwaju igbimọ naa ni pasipọọtu to ṣafihan Tinubu gẹgẹ bii ọmọ orileede Guniea.

Igbẹjọ naa ṣi n tẹsiwaju.

Leave a Reply