Adewale Adeoye
Eeyan meji ni wọn padanu ẹmi wọn lojiji, nigba ti awọn mẹjọ miiran fara pa yannayanna ninu ija igboro kan to bẹ silẹ laarin awọn agbẹ ati Fulani daran-daran kan to wa lagbegbe Suru ati Koko/ Besse, nijọba ibilẹ Suru, nipinlẹ Kebbi. Iṣẹlẹ yii bẹrẹ ni aṣaale ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla yii, ti ko si dawọ duro titi di ọjọ keji, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, to ṣẹṣẹ n lọ silẹ. Gbogbo awọn to fara pa yannayanna nibi ija ọhun lawọn alaṣẹ ijọba ilu naa ti gbe lọ sileewosan tijọba agbegbe naa fun itọju to peye.
Alaga ijọba ibilẹ Suru, Ọgbẹni Mohammed Lawal, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, sọ pe oun ti de agbegbe ibi ti wahala ọhun ti ṣẹlẹ, o ni awọn agbẹ lo dide ija sawọn Fulani darandaran ọhun nigba ti wọn ri i bi wọn ṣe n fi maaluu jẹ oko wọn bajẹ.
Gomina ipinlẹ Kebbi,Ọgbẹni Nasir Idris, toun naa ti ṣabẹwo siluu ti wahala ọhun ti waye ṣapejuwe ija igboro to waye laarin awọn eeyan meji naa gẹgẹ bii ohun ti ko daa rara. Bakan naa lo ba gbogbo awọn ti wọn padanu ẹmi awọn eeyan wọn kedun lori ohun to ṣẹlẹ naa. O si ṣeleri pe ijọba oun maa too fopin sija igboro to maa n waye laarin awọn agbẹ ati Fulani darandaran nigba gbogbo laipẹ.
Atẹjade kan ti Ọgbẹni Ahmed Idris ti i ṣe Alukoro eto iroyin fun gomina ọhun fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘Abẹwo ti gomina ipinlẹ naa lọ ṣe sibi ti iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun ti waye ni lati fopin si laaṣigbo to n figba gbogbo waye laarin awọn agbẹ ati Fulani darandaran agbegbe naa, opin gbọdọ de sọrọ ija naa laipẹ. Ki i ṣohun to daa ki awọn ọmọ iya meji maa bara wọn ja nitori ohun ti ko to nnkan, gomina si ti yọnda miliọnu mẹtala Naira fawọn ẹbi ti wọn padanu ẹmi awọn eeyan wọn ninu ija naa, atawọn to fara pa.
‘‘Bakan naa ni gomina ti gbe igbimọ oluwadii kalẹ, eyi ti kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, ọga ọlọpaa ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, ẹka tipinlẹ yii, ati ọga awọn ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi wa lara wọn kalẹ. Koko iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ ni lati yanju aawọ to wa laarin awọn eeyan mejeeji yii’’.