O ti deewọ fawọn Iya Ọṣun, Iya Ibeji ki wọn maa tọrọ owo ninu ọja-Iyalọja Kwara 

Ibrahim Alagunmu, llọrin

Iyalọja ipinlẹ Kwara, Alaaja Adenikẹ Abdulkareem Lambẹ, ti sọ pe o ti deewọ bayii fun gbogbo awọn iya Onisango, Ọlọbatala ati awọn Iya Ibeji ki wọn maa tọrọ owo lawọn inu ọja gbogbo nipinlẹ naa.

Nigba ti Iyalọja naa n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, lo sọrọ naa di mimọ. O ni gbogbo awọn ọmọ bibi ilu Ilọrin, awọn oloye, ọba, to fi mọ gbogbo awọn mọgaji-mọgaji ni wọn fẹnu ko pe ki wọn maa tọrọ owo niluu Ilọrin mọ, sugbọn inu ọja ni wọn pọ si ju. Eyi lo mu ki gbogbo igbimọ ọlọja ni Kwara ṣepade pẹlu awọn tọrọ kan, to fi mọ awọn agbofinro atawọn olori ẹṣin pe eegun gbogbo awọn eeyan to n tọrọ owo naa ko gbọdọ ṣẹ ninu awọn ọja mọ.

Alaaja Adenikẹ ni ti wọn ba ti tọrọ owo tan ninu ọja to ba di bii ọjọ keji, wọn aa tun pada lọọ ba ẹni to fun wọn lowo pe awọn rina si i, ti wọn yoo si maa lọọ wẹ ori fun wọn lodo, ti wọn aa lu ọlọja miiran ni jibiti, wọn aa gbowo gbowo lọwọ wọn tabi ki wọn sọ ẹlomiran di ẹlẹsin wọn. O ni fun idi eyi, wọn ko gbọdọ wọ inu ọja tọrọ owo mọ, eyikeyii ninu wọn to ba tasẹ agẹrẹ sofin yii, gboro ofin yoo gbe e.

O fi kun un pe gbogbo awọn Iya Ibeji ti wọn n fi awọn ọmọ meji gbowo, ti wọn si tun n da ẹgbẹ silẹ ti gbogbo wọn n ṣe ipade ko ba ofin ẹṣin mu. O rọ gbogbo awọn ọlọja patapata ni Kwara ki wọn ma fun awọn eeyan naa lowo mọ, ẹni ti saara ba ya si, ko mọ ibi ti yoo ti ṣe saara.

Leave a Reply