Nibi ipade tawọn gomina ilẹ Yoruba ṣe pẹlu awọn Mayyeti Allah niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ni wọn ti fẹnu ko pe fifi maaluu jẹ’ko lalẹ tabi loru ti di eewọ kaakiri awọn ipinlẹ to wa ni ilẹ Yoruba gẹgẹ bi Gomina Akeredolu ṣe sofin lọjọ diẹ sẹyin.
Alaga awọn gomina kaakiri ilẹ Naijiria to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, lo dari ipade naa.
Ohun ti eyi tumọ si ni pe ki i ṣe ipinle Ondo nikan ni fifofin de awọn Fulani darandaran lati maa da maaluu lalẹ tabi loru ti mulẹ, kaakiri awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba ni.
Bakan naa ni wọn ṣofin pe awọn Fulani darandaran to ba wa ni ipinlẹ kọọkan gbọdọ forukọ silẹ lọdọ ijọba ipinlẹ ti wọn ba wa.
Yatọ si eyi, wọn tun fofin de awọn Fulani darandaran yii pe wọn ko gbọdọ maa lo awọn ọmọ keekeeke ti wọn ko ti i dagba lati maa da ẹran kiri. O si di eewọ fun ẹnikẹni ninu awọn darandaran yii lati wọ igbo ọba lọna ti ko ba ofin mu.
Siwaju si i, wọn ni ko ni i si aaye fun awọn awọn Fulani darandaran lati kan maa da ẹran kaakiri ibi to ba wu wọn, nitori igbesẹ bẹẹ le da wahala silẹ laarin awọn ati awọn agbẹ. Wọn rọ awọn ẹgbẹ darandaran awọn Fulani yii lati ṣe amulo ọna igbalode ti wọn fi n daran nipa kikọ ibujẹ ẹran igbalode.
Lara ohun ti wọn tun fẹnu ko le lori ni mimu eto aabo dan-in-dan-in nipa lilo awọn ọna mi-in fun eto aabo lati ran ijọba lọwọ.
Fayẹmi waa sọ pe ko si ẹnikẹni to le awọn darandaran yii, nitori ọpọ wọn lo ti pe nilẹ Yoruba daadaa, awọn to n jẹ kiri inu igbo to n hu iwa ọdaran ni awọn ko fẹ niluu mọ.
Wọn fi kun un pe ẹnikẹni to ba huwa ọdaran gbọdọ jiya to tọ si i lai fi ti ẹya ti iru ẹni bẹẹ ti wa tabi iru ẹni to jẹ lawujọ ṣe.