Adewale Adeoye
Olubadamọran Aarẹ Tinubu nipa eto iroyin ati iṣẹ akanṣe lorileede yii, Ọgbẹni Sunday Dare, ti rọ awọn araalu pe ki wọn ṣe suuru gidi fun Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lati gbe iṣakoso ilẹ wa de ebute ayọ, ati pe laipẹ yii ni awọn akọ iṣẹ ati iṣẹ idagbasoke gbogbo ti Tinubu n ṣe laarin ilu maa too foju han gbangba, tawọn araalu si maa janfaani rẹ laipẹ.
Dare to ti figba kan jẹ minisita ere idaraya lasiko ijọba Muhammadu Buhari sọrọ ọhun di mimọ laipẹ yii lori eto pataki kan ti wọn pe e si nileeṣẹ tẹlifiṣan Channels. O ni nnkan maa too bẹrẹ si i daa lorileede yii, nitori pe Aarẹ Tinubu ki i sun, bẹẹ ni ki i wo, lori ọrọ iṣakoso ijọba ilẹ yii. O ni gbogbo ero ọkan Tinubu ni lati ṣe ohun gidi fawọn araalu, paapaa ju lọ, awọn mẹkunu ti wọn dibo fun un lọdun to kọja yii.
Bẹ o ba gbagbe, gbara ti Aarẹ Tinubu depo aṣẹ lo ti yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu, to si tun ṣe awọn ofin kan. Eyi, atawọn ohun mi-in lo fa a towo epo bẹntiroolu fi wọn, ti ohun ti ẹnu n jẹ fi gbowo lori gegere.
Ṣa o, Ọgbẹni Dare ti ni ṣe lo yẹ kawọn araalu maa gboṣuba nla fun Aarẹ Tinubu ni, nitori bi ki i baa ṣe awọn igbesẹ akin kọọkan to gbe ninu ijọba rẹ, wahala nla iba ti ṣẹlẹ lorileede yii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Ṣẹ ẹ mọ pe gbese nla gbaa lowo iranwọ lori epo bẹntiroolu tijọba n san fawọn alagbata epo bẹntiroolu tẹlẹ, kinni ọhun n gbowo danu lapo ijọba wa ni. Lasiko tawọn oloṣelu n ṣepolongo ibo lọdun to kọja yii, gbogbo wọn pata naa lo sọ pe awọn maa dawọ owo ọhun duro, ṣugbọn awọn aṣaaju to ti wa nipo ṣiwaju ko ni igboya to rara lati ṣe bẹẹ, afi Aarẹ Tinubu nikan lo gbe igbesẹ naa. O yẹ ka gboṣuba nla fun un bo ṣe yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa bayii.
Kẹ ẹ si maa wo o, Aarẹ Tinubu ki i sun, bẹẹ ni ki i wo lori ọrọ iṣakoso ijọba Naijiria rara, gbogbo igba lo fi maa n wa lojufo lati ronu kan igbesẹ gidi to ku lori ọrọ ilẹ yii, o si daju pe awọn iṣẹ akin to n ṣe maa too bẹrẹ si i foju han gbangba laipẹ yii.