‘O yẹ ki Makinde yọ olori awọn afọbajẹ Ọyọ danu’ 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bo ṣe mu ki awọn eeyan gbagbọ pe Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo n da awọn araalu Ọyọ duro lati ni ọba tuntun pẹlu bi awọn ṣe fi orukọ ranṣẹ si i, ṣugbọn to kọ lati fọwọ si i ki onitọhun gori itẹ, Igbimọ Itẹsiwaju Ẹsin Ibilẹ ati

Ẹgbẹ Awa Ọmọ Irunmọlẹ, ti sọ pe niṣe lo yẹ ki Gomina Makinde yọ Baṣọrun ilu Ọyọ, Agba-Oye Yusuf Akinade ti i ṣe olori awọn afọbajẹ Ọyọ danu nipo.

Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe orukọ Ọmọọba Lukman Gbadegẹṣin lawọn afọbajẹ ilu Ọyọ, ti gbogbo aye tun mọ si Ọyọmesi, fi ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bii Alaafin tuntun.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin ALAROYE, Aarẹ Igbimọ Itẹsiwaju Ẹsin Ibilẹ ati Ẹgbẹ Awa Ọmọ Irunmọlẹ, Ọmọọba Ọmọtunde Ọbaloye Otukọ Adimula, sọ pe ọna ojooro ati iwa ibajẹ lawọn afọbajẹ gba yan ọmọ oye ti wọn fi orukọ rẹ ranṣẹ si ijọba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Alaafin tuntun iba ti gori itẹ, awọn afọbajẹ to gbabọde ni ko ti i jẹ ko ṣee ṣe, nitori wọn gbe eto yẹn gba ọna to lodi si iṣẹṣe ilu Ọyọ pẹlu ifọwọsowọpọ Baṣọrun, ati diẹ ninu awọn jẹ afọbajẹ ilu Ọyọ.

Awọn Ọyọmesi to ba maa yan ọba tuntun, meje lọ yẹ ki wọn jẹ, meji ninu wọn ti ku, olori awọn Ọyọmesi waa yan eeyan sipo awọn mejeeji to ku yẹn, bẹẹ ijọba nikan lo lagbara lati yan adele Ọyọmesi, ko si iru agbara bẹẹ lọwọ Baṣọrun.

Nitori naa, ọna ti wọn gba mu Ọmọọba Lukman Gbadegẹṣin ti wọn fi orukọ ẹ ranṣẹ sijọba lodi si ilana ti Ọyọ maa n gba yan Alaafin, nitori eyi, ko sẹni to ti i mọ ẹni to maa jẹ Alaafin bayii.

Awọn afọbajẹ ni lati tun eto yẹn bẹrẹ latilẹ, ni ibamu pẹlu aṣẹ ti Gomina Makinde pa fun wọn ṣaaju. Eleyii ko si jẹ tuntun, o ṣẹlẹ lọdun 1970, nigba ti ijọba ẹkun Iwọ-Oorun orile-ede yii, labẹ Ọgagun Adeyinka Adebayọ, paṣẹ fun awọn afọbajẹ Ọyọ lati tun eto yẹn bẹrẹ lẹyin ti ijọba ti fun Ọmọọba Ọranlọla Ladepo ni lẹta pe oun ni yoo jẹ Alaafin, ko too di pe wọn gba iwe ẹsun latọdọ awọn eeyan pe ẹni ti wọn yan yẹn ko tọ lati jọba.

“Lẹyin naa lawọn afọbajẹ gbe Ifa janlẹ, ti ifa si sọ pe ninu gbogbo awọn ọmọ oye to dupo ọba nigba yẹn,

asiko Lamidi Ọlayiwọla ni yoo daa ju lọ. Iyẹn lo ṣe jẹ pe Ọlayiwọla ti i ṣe Alaafin ana ni wọn fi jọba nigba naa”.

Nigba to n sọrọ lori aiṣedeede awọn afọbajẹ ilu naa, Adimula ṣalaye pe ẹẹmeji ọtọọtọ ni Gomina Makinde ti paṣẹ fun wọn tẹlẹ pe ki wọn lọọ tun eto yẹn bẹrẹ, Baṣọrun to jẹ olori awọn Ọyọmesi lo ṣori kunkun, ko faaye silẹ fun ipade debi ti wọn yoo ṣatunṣe kankan. Bo ba jẹ ẹlom-in ni Makinde ni, iyẹn gan-an to ohun tijọba fi maa rọ Baṣọrun loye.

Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni mẹta ninu awọn Ọyọmesi, iyẹn, Agba-Oye Asimiyu Atanda ti i ṣe Agbaakin ilẹ Ọyọ; Lamidi Oyewale (Samu ilẹ Ọyọ), ati Baalẹ Ajagba, Odurinde Oluṣegun, sọ pe awọn ko fara mọ ọna ti awọn afọbajẹ yooku awọn gba yan ẹni ti wọn forukọ ẹ ranṣẹ si ijọba gẹgẹ bii Alaafin tuntun nitori wọn ko gbe eto naa gba ọna to tọ.

Leave a Reply