Monisọla Saka
Omọ ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ to n ṣoju Aarin Gbungbun ipinlẹ Borno, Sẹnetọ Abba Aji, ti rọ Aṣiwaju ẹgbẹ APC, Bọla Tinubu, lati ṣatilẹyin fun Igbakeji Aarẹ wa, Yẹmi Ọṣinbajo, to ti fi erongba rẹ lati dupo aarẹ han, nitori pe ọkunrin naa ni awọn ololufẹ kaakiri orileede yii ni.
O sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. O ni, ‘Aṣiwaju jẹ aṣaaju to daa ninu ẹgbẹ wa, ojuṣe rẹ yii paapaa lo mu ko fa Ọṣinbajo kalẹ gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ilẹ wa pẹlu bi Ọṣinbajo ti ṣe ṣiṣẹ takuntakun ninu ijọba yii, ti eyi si ti jẹ iwuri fun Aarẹ Buhari ati awọn ọmọ orileede yii paapaa.
‘Gẹgẹ bii aṣaaju, nigba ti o ba ti mu aba rere wa, o gbọdọ gba iru aba naa laaye lati dagba. Iru rẹ ni ti Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, to jade lati dupo aarẹ yii. O ni igbesẹ to kan bayii ni fun un lati ṣe atilẹyin fun Ọṣinbajo lati di aarẹ Naijiria lọdun 2023.’
Abba ni, ‘‘Mo ti wa ninu oṣelu lati ọdun diẹ sẹyin, mo si le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe awọn oludibo ti gbọn daadaa, wọn ti ti mọ ohun to tọ ati eyi to yẹ si i ju ti atẹyinwa lọ.
‘‘Gbogbo ipolongo lọlọkan-o-jọkan lo n tọka si i bi onikaluku ṣe lagbara si, to si n fi agbara awọn araalu paapaa han. Ṣugbọn ohun ti gbogbo eyi to ti waye n tọka si ni pe Ọṣinbajo lo n lewaju ni anfaani lati jawe olubori ju ẹnikẹni lọ.