O ṣẹlẹ, ọjọ ori mẹta ọtọọtọ ni iwe-ẹri Tinubu ni

Faith Adebọla

 Ọkan lara awọn aṣiri to fara han ninu awọn akọsilẹ ati iwe-ẹri ti Fasiti Chicago ti olori orileede wa, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti kawe, iyẹn Chicago State University, to wa lorileede Amẹrika, ko kalẹ fun Atiku Abubakar, gẹgẹ bii aṣẹ ile-ẹjọ giga Illinois, ni ọrọ ọjọ-ọri baba agbalagba naa.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun ni Tinubu maa n ṣayẹyẹ ọjọọbi rẹ. Eyi to ṣe lodun yii lo si fi sọ pe ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin loun pe loke eepẹ.

Eyi lohun to wa ninu akọọlẹ ati awọn ẹri ti Tinubu ko kalẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission, INEC, tori March 29, 1952 lo kọ silẹ labẹ ibura pe wọn bi oun.

Amọ ninu awọn akọọlẹ Fasiti Chicago to tẹ Atiku Abubakar lọwọ bayii, March 29, 1954 lo wa lakọọlẹ gẹgẹ bii ọjọ-ibi rẹ. Eyi fihan pe ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin ni Tinubu jẹ lọdun yii, eyi ko si dọgba pẹlu ti INEC, o fọdun meji yatọ sira.

Siwaju si i, ninu awọn akọsilẹ kan ti fasiti naa tun ko kalẹ, eyi ti Tinubu fun wọn lasiko to fẹẹ wọle sileewe naa, ati lawọn igba to n kawe nibẹ nibẹrẹ, March 29, 1955 lo wa ninu awọn iwe-ẹri naa gbogbo. Eyi tun fi ọdun mẹta yatọ si sabukeeti to wa lọdọ INEC, ati eyi to gba jade ni Fasiti Chicago gan-an.

Ni bayii, awọn akọsilẹ yii fihan pe Aarẹ Tinubu yoo jẹ ẹni ọdun mejidinlaaadọta, tabi mọkandinlaaadọta, tabi kẹ, ẹni ọdun mọkanlelaaadọta.

Latari eyi, Oluranlọwọ pataki si Atiku Abubakar lori eto ibanisọrọ, Ọgbẹni Phrank Shaibu, fi ẹfẹ sọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa yii pe: “Ninu gbogbo ẹda t’Ọlọrun da, Tinubu nikan lo jẹ ọkunrin, to si tun jẹ obinrin lẹsẹ kan naa, oun nikan lo ni ọjọ-ibi meji, mẹta lẹẹkan naa. Akanda ẹda kan to wa latọrun lọkunrin yii maa jẹ o, tabi ko jẹ pulanẹẹti Jupiter lo ti ja bọ saye,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply