Ọba Iragbiji pariwo: Ẹ gba mi o, Ẹrọ Arikẹ fẹẹ pa mi o

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Aragbiji ti ilu Iragbiji, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrasheed Ayọtunde Ọlabomi, ti fẹsun kan Alhaja Falilat Oyetunji to jẹ oludari ileeṣẹ Ẹrọ Arikẹ pe o ti ran awọn agbanipa niṣẹ lati gbẹmi oun ati mẹta lara awọn ọmọ ilu oun.

Ninu fidio oniṣẹju mẹrin ataabọ ti Ọba Ọlabomi gbe sori ikanni feesibuuku rẹ lo ti ke si gomina ipinlẹ Ọṣun, ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, awọn ọmọ bibi ilu Iragbiji lọkunrin lobinrin atawọn ọmọ orileede yii lati gba oun lọwọ ẹni to fẹẹ pa oun naa.

Ọba Ọlabomi sọ pe “Gbogbo ẹyin ọmọ Naijiria, ẹyin agbofinro, ọga agba fawọn ọlọpaa, kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, ẹyin ajọ ọtẹlẹmuyẹ, gbogbo yin ni mo ki.

“Mo fẹẹ sọrọ lori Falilat Arikẹ, a gbọ ọ, a si ri ẹri aridaju pe o ti ko awọn agbanipa wọnu ilu lati maa ṣọ irin mi ati ti Baalẹ Ọlọrunda n’Iragbiji, Jimọh Ojeran, ati awọn ọmọ wa meji mi-in, Abdulrasheed Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si Jimade, pẹlu Wasiu Babalọla ti gbogbo eeyan mọ si Oluaye.

“O ti sanwo nla fun wọn, ki Ọlọrun ma gba a laaye lati gbẹmi wa. Mo n ke si Gomina Gboyega Oyetọla, Kọmiṣanna Falẹyẹ, awọn DSS, ọga agba ọlọpaa, ẹ jọọ, ẹ gba wa o.”

Aragbiji fi kun ọrọ rẹ pe awọn ko ṣe nnkan kan fun obinrin oniṣowo naa to fi n lepa ẹmi awọn mẹtẹẹta.

Ṣugbọn ninu fidio kekere kan ti Erọ Atikẹ to wa ni ilu Mecca bayii gbe sori ikanni rẹ lati fesi si ẹsun ti wọn fi kan an yii lo ti sọ pe ko sohun to jọ ẹsun ti kabiyesi fi kan oun. O ni to ba jẹ pe loootọ ni ohun ti ọba alaye naa wi, ki gbogbo adura toun waa gba ni Mecca ja sasan. Obinrin yii ni oun ki i ṣe onijangbọn, oun ko si lagbara lati pa ẹnikẹni. O ni iṣẹ aanu ni awọn eeyan mọ oun mọ, ki oun maa fun awọn alaini ni nnkan. O fi kun un pe aafaa mẹfa ni oun ko wa si Mecca yii, ni awọn ti wọn ko de ilu naa ri. Bẹẹ lo sọ pe ija ilara ni ohun to n ṣẹlẹ, nitori oun ko ni wahala pẹlu ẹnikẹni bii ti i wu ko mọ.

O waa ṣeleri pe bi oun ba ti de Kaaba loun maa ṣe fidio mi-in, toun si maa tu awọn aṣiri kan faye gbọ.

Leave a Reply