Florence Babaṣọla
Ogiyan ti ilu Ejigbo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Ọmọwọnuọla Oyesọsin, ti ke si Gomina Gboyega Oyetọla lati ba wọn yi orukọ ileewe Wọle Ṣoyinka Government High School, pada si Akinjole Government Secondary School.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2015, ni Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla ṣi ileewe nla kan to fi miliọnu lọna ọtalelaaadọrin o din mẹwaa naira (#750m) kọ siluu Ejigbo, to si pe orukọ rẹ ni Wọle Ṣoyinka Government High School.
Ṣugbọn lasiko ipade kan ti ọfiisi oludamọran pataki fun Gomina Oyetọla lori ibaṣepọ awọn araalu ṣe pẹlu awọn eeyan ilu Ejigbo ninu gbọngan ilu naa ni Ọba Oyesọsin ti sọ pe awọn fẹ kijọba yi orukọ naa pada si orukọ baba-nla awọn to tẹ ilu naa do, Akinjole.
Kabiyesi ṣalaye pe yatọ si bi mimu ayipada ba orukọ naa yoo ṣe mu inu awọn eeyan ilu naa dun, o tun jẹ ọna lati bu ọla ati iyi fun awọn alalẹ ilu ọhun.
Ogiyan fi kun ọrọ rẹ pe titi lae ni ilu Ejigbo yoo maa ranti Gomina Oyetọla fun ipa ribiribi to ti ko ninu idagbasoke ilu naa lẹnu iwọnba asiko to ti de ori aleefa.
O ni “Aimọye awọn iṣẹ idagbasoke ni gomina ti ṣe ninu ilu wam eleyii to si ti mu ki aye tun gbẹdẹmukẹ si i fun awọn eeyan wa. Lara wọn ni oju-ọna ninu ilu yii to ti mu ki irinajo kaakiri rọrun fun wa.
“Inira ti a la kọja latari irinajo laarin Ejigbo si Oṣogbo fọpọ ọdun ti dohun itan bayii. A ko le gbagbe atunṣe ileewosan General Hospital ati Primary Health Center wa, bẹẹ naa si ni atunṣe ileeṣẹ panapana ti ilu Ejigbo, to fi mọ atunṣe biriiji Sagan ati bẹẹ bẹẹ lọ.’’
Oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ ibaṣepọ awọn araalu, Ọgbẹni Ọlatunbọsun Oyintiloye, tẹnu mọ ọn pe eredi ipade tileeṣẹ naa n ṣe kaakiri ni lati mọ ẹdun ọkan awọn araalu, ati ki awọn araalu naa le nipa lori ọrọ idagbasoke ipinlẹ Ọṣun.
O dupẹ lọwọ awọn araalu Ejigbo fun aduroti wọn fun iṣejọba Gomina Oyetọla, o si ṣeleri pe gbogbo ibeere wọn nijọba yoo gbe yẹwo.