Ọbabinrin Elizabeth Keji ti ku o!

 

Faith Adebọla

Elizabeth keji, ọbabinrin to pẹ lori itẹ ju lọ lorileede United Kingdom, ti dagbere faye. Obinrin naa mi eemi ikẹyin lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an ọdun 2022 yii, ni Balmora, pẹlu awọn ọmọ ati mọlẹbi rẹ lẹgbẹ rẹ, gẹgẹ bi ikede ti wọn ṣe laafin Buckingham to n lo. Ẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un ni i ṣe.

Ọbabinrin yii ni saa iṣakoso rẹ ṣi pẹ ju lọ lorileede United Kingdom, aadọrin ọdun lo fi ṣakoso, olori ijọba ilẹ Gẹẹsi mẹẹdogun lo ba a lori itẹ ọba.

O gori itẹ loṣu keji, ọdun 1952, lẹyin iku baba rẹ, Ọba George kẹrin, wọn si ṣayẹyẹ igbade rẹ lọdun 1953 to tẹle e.

Latigba tawọn dokita ti kede pe aarẹ agba ti mu mama naa lọjọ Wẹsidee lawọn ọmọ rẹ ọmọ rẹ mẹrẹẹrin, ti rinrinajo lọ sọdọ mama wọn, ti wọn si duro ti i to fi dakẹ.

Gẹgẹ bii ofin ọba jijẹ lorileede naa, akọbi ọmọ rẹ, Charles, ni yoo rọpo rẹ lẹsẹkẹsẹ, oun si ni yoo ṣaaju ayẹyẹ idaro ati eto isinku ti yoo bẹrẹ lọjọ Ẹti, Furaidee.

Tẹ o ba gbagbe, oloogbe yii wa lara awọn alaṣẹ ilẹ United Kingdom ti wọn da ijọba pada fawọn oloṣelu ilẹ Naijiria lọdun 1960 ta a kuro labẹ ijọba oyinbo amunisin, ta a gbominira, obinrin naa si wa nipo aarẹ ilẹ wa fọdun mẹta, ki Naijiria too gba ominiran patapata lọdun 1963, lẹyin ti wọn ṣatunṣe si iwe ofin ta a n lo nigba naa.

Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹrin ọdun 1926 ni wọn bi oloogbe Elizabeth keji.

Ọjọ kẹsan-an oṣu kẹrin ọdun 2021 to kọja lọkọ rẹ, Ọmọọba Philip, ku lẹni ọdun mọkandinlọgọrun-un, igbeyawo wọn si wa fun ọdun mẹtalelaaadọrin.

Kari aye lawọn alaṣẹ atawọn eeyan pataki pataki ti n rọjọ iṣẹ ibanikẹdun si orileede United Kingdom, wọn ni ẹni rere ni Ọbabinrin to lọ ọhun.

Leave a Reply