Kazeem Ọlajide
Oga agba tẹlifiṣan Shara, Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ti sọ pe Olori ile-igbimọ asọfin Eko, Mudashiru Ọbasa, lo wa nidii bi awọn janduku kan ṣe kọlu awọn to n ṣe iwọde niwaju ile-igbimọ aṣofin Eko.
Ọkunrin oniroyin to nileeṣẹ Sahara Reporters yii sọ pe Agege lo ti lọọ ko awọn janduku ọhun wa, ti wọn si ṣe awọn eeyan leṣe rẹpẹtẹ.
Ọrọ di bo o lọ o yago laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti awọn janduku tọọgi kan ya bo awọn ọdọ orilẹ-ede yii ti wọn n ṣe iwọde ta ko idasilẹ ẹṣọ kan ti ijọba tun pe ni SWAT.
Obinrin kan to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ṣalaye pe lojiji ni danfo kan de saarin awọn ero, ki awọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, niṣe ni wọn fa ọbẹ ati ada yọ pẹlu awọn ohun ija oloro mi-in, ti wọn si fi n le awọn eeyan kiri.
Mudashiru Ọbasa, olori ile-igbimọ aṣofin Eko naa ti sọrọ, alaye to ṣe ni pe ko si ọwọ oun ninu bi awọn tọọgi kan ṣe kọlu awọn ti wọn n ṣe iwọde.
O sọ pe opurọ aye ti ọrọ ẹ ko ṣee tẹle ni Ọmọyẹle Ṣoworẹ, nitori o pẹ to ti kuna ninu erongba ẹ lati maa ko awọn ero jọ fun ijangbara ti ko nitumọ.
Asọfin yii fi kun un pe ti awọn ọdọ loun n ṣe, nitori oun ba wọn ṣepade, ti asọyepọ to nitumọ si waye daadaa pẹlu.