Faith Adebọla
Yooba bọ, wọn lohun a ba mọ-ọn ṣe, bii idan ni i ri, bii igba ti ikun n dabira loko ẹpa lọrọ jijawe olubori ninu ibo sileegbimọ aṣofin Eko jẹ fun Ọmọwe Mudaṣiru Ajayi Ọbasa, ọkunrin naa tun ti wọle ibo lati ṣoju awọn eeyan agbegbe idibo Agege Kin-in-ni, ninu eto idibo awọn aṣofin to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, eyi si ni igba kẹfa ọtọọtọ, lati ọdun 2003, ti wọn ti n fibo da Ọbasa pada sileegbimọ aṣofin ọhun.
Adari eto idibo awọn aṣofin naa to ṣoju ajọ INEC, Ọgbẹni Lukman Adeniji, lo kede ijawe olubori Ọbasa, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii.
Nigba to n ka abajade esi idibo naa ni gbọngan ti wọn ti ṣe akojọ ati aropọ ẹ l’Agege, Lukman ni ẹgbẹ oṣelu mẹjọ ọtọọtọ ni wọn fa oludije kalẹ fun ipo aṣofin naa, amọ ibo Ọbasa, ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lo tẹwọn ju lọ, ẹgbẹrun lọna mẹtadinlogun, o le igba ati mẹrinla (17,214) ibo lo ni, nigba ti ẹni to ṣe ipo keji, Raheem Alani, latinu ẹgbẹ oṣelu Labour Party, ni ibo ẹgbẹrun mẹrin din diẹ, (3,933). Kafayat Biobaku ti ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, (ADC) ni ibo mejilelọgọta pere, nigba ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ni ibo ẹgbẹrun kan aabọ ati diẹ (1,609).
Yatọ si pe Ọbasa yoo di aṣofin to ti i pẹ ju lọ nilegbimọ l’Ekoo, saa meji lo ti fi ṣe olori awọn aṣofin naa, lati ọdun 2015.