Obi nikan lo pegede ju lọ lati di aarẹ Naijiria – Afẹ Babalọla

Monisọla Saka

Oludasilẹ ileewe giga Fasiti aladaani to wa l’Ado Ekiti, Oloye Afẹ Babalọla, to tun jẹ agba lọọya, ti sọ pe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, lo duro ire ju lọ, oun lo si yẹ ko bẹrẹ si i maa tukọ orilẹ-ede yii, lẹyin ti aarẹ Buhari ba pari saa eto iṣejọba rẹ.

O ṣalaye siwaju pe awọn ti wọn n ta ko Obi naa lawọn ti wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe sun ilẹ Naijiria de ipo to da bii omi adagun to wa lọwọlọwọ bayii.

Ninu ọrọ ẹ lo ti ni, “Afi to ba jẹ pe iwọ naa wa lara awọn ti wọn sin Naijiria debi to de yii ni, ko si bo o ṣe maa ta ko ọdọmọkunrin bii Peter Obi, to ṣi lagbara lati ṣiṣẹ, ti ko si lakọsilẹ iwa ibajẹ kan to le ko abawọn ba orukọ ẹ latẹyinwa, eeyan to kawe, to si loye lori, lati di aarẹ ilẹ Naijiria ni”.

Baba agbalagba ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un, ti yoo ṣami ayẹyẹ ọgọta ọdun to ti n ba iṣẹ agbẹjọro bọ ọhun sọ pe iwa kan wa to pa oun ati Obi pọ, eyi naa si ni ifẹ fun ẹkọ to ye kooro.

O ni, “Nnkan kan wa to jẹ awa mejeeji la jọ ni in, nnkan to jẹ pe bemi ṣe nifẹẹ si i loun naa ni in ni pe yoo faaye gba eto ẹkọ to daa ninu iṣejọba ẹ. Gẹgẹ bi gbogbo yin ṣe lanfaani ẹ, emi o riwee igbalode ka, mi o kawe mẹwaa ti girama, ṣugbọn nitori ti mo ni ipinnu ati iwa akinkanju lọkan, mo fara da a. Labẹlẹ ni mo kawe alatọwọdọwọ ti mo fi gbawe ẹri A-Level, irufẹ ọna ikawe yii naa ni mo fi ṣedanwo aṣewọle si ileewe giga fasiti.

“Ti ki i ba a ṣe ti ẹkọ iwe, mi o ba ma debi ti mo wa lonii yii, nitori idi eyi lo ṣe jẹ pe pẹlu ogo Ọlọrun, lẹyin ti mo ti ṣiṣẹ agbẹjọrọ laṣeyege fun ọpọlọpọ ọdun, ni mo fi jẹ nnkan ti mo jẹ lonii yii”.

Baba yii waa sọ pe oun yoo ṣayẹyẹ alarinrin fun iṣami ọgọta ọdun toun ti n ba iṣẹ lọọya bọ lọdun yii, ati pe pẹlu ogo Ọlọrun, Peter Obi yoo wa nibẹ, nitori oun lo pegede ju lọ lati bọ sipo aarẹ ilẹ Naijiria.

 

Leave a Reply