Faith Adebọla, Eko
Ṣe ẹ ranti orekelẹwa obinrin kan, Chidinma Pearl Ogbulu, to ha ẹbun kẹẹgi bẹntiroolu ni pati fawọn alejo ẹ l’Ekoo, lọjọsi? Obinrin naa ti foju bale-ẹjọ, o si ti n ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ, niwaju adajọ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nijọba ipinlẹ Eko wọ afurasi ọdaran naa lọ sile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe l’Oṣodi, ẹsun mẹrin ọtọọtọ ni wọn ka si i lẹsẹ.
Lara awọn ẹsun naa ni pe o mọ-ọn-mọ fẹmi awọn eeyan sinu ewu ni pati ẹ, wọn lo huwa to le da yanpọnyanrin silẹ lawujọ, wọn tun lo n ṣowo ti ko bofin mu nipa titọju bẹntiroolu to le gbina sibi ti ko yẹ, bẹẹ si ni ko gba aṣẹ lati ṣe nnkan to ṣe.
Lẹyin ti wọn ti ka ẹsun rẹ tan, obinrin naa loun o jẹbi pẹlu alaye, nile-ẹjọ ba sun igbẹjọ rẹ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Ile-ẹjọ tun yọnda beeli silẹ fun afurasi ọdaran naa, ko le maa tile waa jẹ ẹjọ rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta yii, ni Chidinma ṣenawo nla ni gbọngan igbalejo Havillah Events Centre to wa ni Victoria Island, l’Erekuṣu Eko, bẹẹ ni fidio gbe obinrin naa ati awọn alejo to n ha kẹẹgi bẹntiroolu fun jade, fidio naa si ja ranyin lori ẹrọ ayelujara.
Ko pẹ lẹyin eyi nijọba ipinlẹ Eko bẹnu atẹ lu iwa tobinrin naa hu, awọn ọlọpaa si lọọ fi pampẹ ofin gbe e lati ṣewadii, ki wọn too foju rẹ bale-ẹjọ.