Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbakeji alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ni Guusu Iwo-Oorun nigba kan ri, Alhaji Shuaib Oyedokun, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Party (APC) nipinlẹ Ọṣun bayii.
Bakan naa ni oludije funpo gomina ninu idibo abẹle ti ẹgbẹ PDP Ọṣun ṣe lọdun 2022, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, ti juwọ si ẹgbẹ naa bayii, o si ti kọja sinu ẹgbẹ APC.
Nibi ayẹyẹ nla ti wọn ṣe niluu Oṣogbo, lati gba awọn eekan mejeeji yii ati ọpọ awọn alatilẹyin wọn wọle, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ni gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti sọ pe ọdun 2026 lopin irinajo fun ẹgbẹ PDP l’Ọṣun.
Oyetọla ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ PDP Ọṣun ṣe n ya wọnu ẹgbẹ APC latigba ti awọn ti kuro nijọba.
O ni ko si ẹnikankan to kuro ninu ẹgbẹ APC, nitori wọn mọ pe ifasẹyin ranpẹ lo ba ẹgbẹ naa, dipo bẹẹ, ṣe lawọn aworoṣaṣa ninu ẹgbẹ PDP n darapọ mọ awọn lojoojumọ.
Eredi eleyii, gẹgẹ bi Oyetọla ṣe wi, ni pe awọn araalu ti dan ile ọkọ meji wo, wọn ti mọ iyatọ laarin awọn ẹgbẹ Onitẹsiwa ati ẹgbẹ onimọ-tara-ẹni-nikan.
O sọ fun awọn ti wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ APC pe ko si iyatọ kankan laarin awọn to ti wa ninu ẹgbẹ tẹlẹ atawọn ti wọn ṣẹṣẹ darapọ, o ni ṣe lawọn yoo jọ kọmọlubọ titi ti ipinlẹ Ọṣun yoo fi pada sọwọ ẹgbẹ Onitẹsiwaju.
Ninu ọrọ Alhaji Shuaib Oyedokun, o ni oun fi ẹgbẹ PDP silẹ nitori wọn ti pa ilana da, wọn ti kuro lori ipilẹ ti awọn baba nla ẹgbẹ naa fi lelẹ.
Bakan naa ni Babayẹmi ṣeleri lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ẹgbẹ naa, ki iṣejọba ẹgbẹ PDP le wa sopin nipinlẹ Ọṣun lọdun 2026.
Lara awọn ti wọn wa nibi eto naa ni Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore, Sẹnetọ Ajibọla Baṣiru, alaga ẹgbẹ naa l’Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal, Oloye Titi Laoye Pọnnle ati bẹẹ bẹẹ lọ.