Faith Adebọla
Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ti tẹ ọdaju abiyamọ kan, Abikẹ Ọlọnade, niṣe lo lọọ ji ọmọleewe sẹkọndiri kan gbe lagbegbe Ọbada-Oko, nitosi Abẹokuta, nigba ti aṣiri rẹ si tu, ti wọn mu un, ti wọn si beere ibi to tọju ọmọọlọmọ ọhun si, o lọna ọmọ naa ti jin, o loun ti ta a lati fi ṣowo ẹru lorileede Libya.
SP Ọmọlọla Odutọla, ti i ṣe alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.
O ni ọmọọlọmọ ti afurasi ọdaran ọhun ta bii ẹru yii, ọmọọdun mẹrindinlogun ni, ileewe aladaani kan ti wọn n pe ni ‘Adeoye Lambo Secondary School’, to wa niluu Ọbada-Oko, lọmọ ọhun n lọ, afi bo ṣe ṣadeede dawati, ti ko si sẹni to mọ bi ọmọ ti wọn forukọ bo laṣiiri naa ṣe rin.
Lẹyin ti iṣẹlẹ yii de etiigbọ awọn ọlọpaa, kia lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ si i fimu finlẹ, itọpinpin ti wọn si ṣe ọhun ṣamọna wọn de ọdọ afurasi yii, Abikẹ.
Wọn lobinrin naa kọkọ sọ pe oun o mọ ọmọ ti wọn n wa, oun o ri i ri, oun o si mọ ibi to wa, amọ nigba ti wọn tẹ ẹ ninu daadaa, o jẹwọ pe loootọ loun mọ ọmọ naa, oun loun ji i gbe, ṣugbọn ki i ṣe lati gbowo lọwọ awọn obi ẹ, tabi lati ṣe e ni ṣuta o, o loun fi i ṣọwọ si awọn ti wọn n wa ọmọọdọ nilẹ okeere ni, o ni wọn ti mu un lọ sorileede Libya lọhun-un.
Alukoro ni awọn ko ti i le sọrọ lori owo to gba to fi huwa aidaa s’ọmọ ọlọmọ atawọn obi rẹ, awọn ṣi n ba iwadii ijinlẹ niṣo lati mọ awọn onigbọwọ ati awọn alajumọṣiṣẹpọ ti wọn kun afurasi yii lọwọ, ti wọn ṣe ohun ti wọn ṣe.
O ni lẹyin iwadii, Abikẹ yoo foju bale-ẹjọ, yoo lọọ ṣalaye ẹnu ẹ fun adajọ daadaa.