Ọdaju abiyamọ ju ọmọ oojọ sigbo ni Kwara 

 

 Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti doola ẹmi ọmọ tuntun to jẹ ọmọ oojọ kan ti wọn ri he ninu igbo lagbegbe Dokoyirigi, Patigi, nijọba ibilẹ Ẹdu, nipinlẹ Kwara.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni agbẹnusọ ajọ naa, Babawale Zaid Afolabi, fi atẹjade kan lede pe ọkan lara awọn ọṣiṣẹ ajọ naa ri ọmọ tuntun to jẹ ọmọ oojọ kan to jẹ obinrin ni owurọ kutukutu ọjọ Ẹti, ọṣẹ yii.

Wọn ti gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu Jẹnẹra to wa niluu Patigi fun itọju to peye, wọn si ti doola ẹmi ọmọ naa bayii.

Gbogbo akitiyan awọn ẹsọ alaabo yii lati ṣawari iya ọmọ ọhun lo ja si pabo. Afọlabi ni ọkan lara oṣiṣẹ ileewosan Tsado Racheal, ti gba lati maa gbe ọmọ naa lọ sile rẹ fun itọju, ti wọn si ti n to gbogbo iwe bayii, ko le maa gbe ọmọ tuntun naa lọ.

Leave a Reply