Ọdaju lawọn eleyii o, ọmọọlọmọ ni wọn ki mọlẹ ti wọn fipa ba laṣepọ l’Ejigbo

Faith Adebọla, Eko

 

 

Ọlọrun nikan lo mọ’ru ẹmi to ko sawọn ọdọ mẹrin tẹẹ n wo ninu fọto yii ninu o, Jimoh Kamọru, Lukman Basit, Sunday Alẹshinlọyẹ ati Ifẹoluwa Alabi, ọmọ ọdun mẹrindinlogun lawọn mẹrẹẹrin, niṣe ni wọn yọ ada atọbẹ sọmọbinrin kan tiyaa ẹ ran niṣẹ l’Ejigbo, ni wọn ba fipa ba a laṣẹpọ.

Alukoro ọlọpaa to fi iṣẹlẹ yii to ALAROYE leti sọ pe Tawa Abiọdun lorukọ iya ọmọbinrin tawọn afurasi yii ki mọlẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja yii, Ojule Igba, (200), Ibudokọ Mafo, lọna Idimu, Ejigbo, lawọn n gbe, iya naa sọ ni teṣan ọlọpaa pe ounjẹ loun n se lọwọ ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ toun fi ran ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri naa niṣẹ pe ko ba oun ra nnkan ni Opopona Lafẹnwa ti ko ju opopona kẹta sile wọn lọ.

O to kọmọ naa pada de, wọn reti ẹ titi, wọn ko ri i, niya ẹ ba kegbajare sawọn ti wọn jọ n gbele, awọn ọkunrin kan si dide, wọn ba a tọpasẹ ọmọ naa lọ.

Wọn ni bi wọn ṣe n lọ ni wọn pade ọmọbinrin ọhun to n sunkun, lọmọ ba ṣalaye ohun toju ẹ ri, o lawọn bọisi kan ni wọn rẹbuu oun lọna koun too de ibi to ti fẹẹ ba iya oun ra nnkan, o ni wọn yọ ada ati ọbẹ soun pe toun ba fi le lọgun pẹnrẹn, awọn maa ṣa oun pa ni, ni wọn ba wọ oun lọ sile kan ni Ojule kẹtalelọgbọn, Opopona Alaaji Obe, l’Ejigbo kan naa, ibẹ ni wọn ti fipa ba ọmọ yii laṣepọ, ti wọn si ṣe ọmọ ọlọmọ yankanyankan.

Oru ọjọ naa niya ọmọ yii atawọn aladuugbo tẹle e lati lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ejigbo, ni DPO ọlọpaa fi ṣeto lati lọ sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ka awọn mẹrin mọ ile naa, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe wọn.

Adejọbi lawọn afurasi ọdaran naa ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ lawọn huwa buruku ọhun. Wọn tun jẹwọ pe awọn kan lara awọn ti sa lọ, bẹẹ ni wọn ba ada meji, ọbẹ ati ọpọlọpọ egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni, ti wọn we mọ beba nibẹ.

O lawọn ti fọrọ naa to kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko leti, o si ti paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo wọn lọ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni ẹka to n wadii ọrọ awọn majeṣin nileeṣẹ ọlọpaa, Panti, ni Yaba, ni wọn wa bayii. O lawọn agbofinro ṣi n wa awọn to ku ti wọn fẹsun kan pe wọn n lọwọ siwa ibajẹ naa.

Wọn ti mu ọmọbinrin naa lọ sileewosan fun ayẹwo ati itọju, wọn si ti ṣeto bawọn ọdaju afurasi ọdaran wọnyi ṣe maa foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply