Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ Majisireeti kan to wa niluu Ado-Ekiti, ti paṣẹ pe ki ọmọdekunrin kan, Ọmọyẹni Ibukun, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn.
Ibukun to jẹ ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni ilu Ikẹrẹ-Ekiti, ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti gbe wa si ile-ẹjọ naa, pẹlu ẹsun pe o pa ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹfa niluu, o ni pe awọn mẹfa yii ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun miiran.
Gẹgẹ bii agbefọba ile-ẹjọ naa, Ọgbẹni Caleb Leramọ ṣe sọ, o ni Ibukun ni wọn fi ẹsun apaayan ati ṣiṣe ẹgbẹ okunkun kan, ẹṣẹ meji yii ni wọn sọ pe Ibukun ṣẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii.
Agbefọba yii sọ pe ọdaran naa jẹwọ pe lọjọ ti ija ajaku akata kan waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji ni ilu Ikẹrẹ-Ekiti, ni o yin ibọn pa Ọmọlade Ọlasunkanmi, Samuel Oluwatimilẹhin ati awọn mẹrin mi-in ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Agbefọba yii sọ pe ọdaran naa jẹ gbaju-gbaja ninu ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ni ilu Ikẹrẹ-Ekiti, awọn ọlọpaa si ti n wa a ko too ṣẹ ẹṣẹ naa.
Ẹṣẹ yii ni Ọgbẹni Lerama sọ pe o ta ko ofin 319 to jẹ ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ekiti ti ọdun 2012 ati apa kẹrin ninu iwe ofin to de ẹnikẹni lati ṣe ẹgbẹ okunkun ni ipinlẹ Ekiti ti ọdun 2017.
O tun sọ pe ki ile-ẹjọ fi ọdaran naa pamọ si ọgba ẹwọn titi di igba ti oun yoo gba esi lati ile-iṣẹ ijọba to n gba awọn adajọ nimọran.
Ṣugbọn gbogbo ẹbẹ ti ọdaran naa bẹ ile-ẹjọ naa lo ja si pabo, ṣugbọn nigba to n gbe igbẹjọ rẹ kalẹ, adajọ ile-ẹjọ naa, Arabinrin Titilayọ Ọlaolọrun, paṣẹ pe ki ọdaran naa ṣi wa lọgba ẹwọn titi di igba ti imọran yoo jade lati ileeṣẹ ijọba.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa si ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an ọdun yii.