Ọdalẹ ni mi ti mo ba fi kọ lati dupo aarẹ-Ọsinbajọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti ni aifẹẹ ja awọn eeyan orilẹ-ede yii kulẹ lo ṣokunfa bi oun ṣe pinnu lati dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọsinbajọ sọrọ yii lasiko abẹwo to ṣe si ipinlẹ Ondo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lati rọ Gomina Rotimi Akeredolu atawọn aṣaaju ẹgbẹ APC ki wọn le ṣatilẹyin fun un ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ APC to fẹẹ waye ninu oṣu Karun-un, ọdun ta a wa yii.
Igbakeji Aarẹ ni oun ti gbaradi, bẹẹ loun ti ṣetan ,ati dupo aarẹ ninu eto idibo gbogbogboo ọdun 2023, nitori pe bii iwa ọdalẹ ni yoo jẹ si awọn eeyan Naijiria ti oun ba fi kuna ati lo awọn iriri ti oun ti ni sẹyin laarin ọdun meje ti oun fi jẹ Igbakeji Aarẹ fun itẹsiwaju ati idagbasoke orilẹ-ede yii.
O ni oun mọ-ọn-mọ fi ara oun silẹ lati sin awọn eeyan ni, nitori pe awọn ọmọ Naijiria nilo aṣiwaju ti yoo mu wọn kuro ninu aginju wa si gbangba.
Ọjọgbọn ninu imọ ofin ọhun ni ko sohun to buru rara ti oun naa ba pinnu lati lo awọn ibaṣepọ ti oun ti ni kaakiri agbaye fun igbega Naijiria, niwọn igba ti ko ti ni awọn eeyan kan lara lati fi ẹmi wọn lelẹ nitori ifẹ orilẹ-ede wọn.
Ọṣinbajọ ni oye ye oun kedere pe ko sohun ti eeyan le da laye lai si imọtẹlẹ Ọlọrun nibẹ, o ni iṣẹ nla ni wọn gbe le oun lọwọ pẹlu ipo Igbakeji Aarẹ ti oun di mu fun odidi ọdun meje, awọn iriri ọhun lo ni o gbo oun laya ti oun fi fẹẹ dije dupo aarẹ nitori ko tun si ifun kan ninu oromọdiyẹ Naijiria ti oun ko mọ daju.
Nigba to n fun Ọṣinbajọ lesi ọrọ rẹ, Gomina Akeredolu ni ko si ani-ani pe gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ lati ipinlẹ Ondo ni wọn fẹran rẹ, ti wọn si ni ọwọ to ga ju lọ fun un.
Aketi ni agbọye lawọn gbọ gbogbo ọrọ to ti ba awọn sọ, ṣugbọn Igbakeji Aarẹ gbọdọ mọ pe ọwọ Ọlọrun nikan ni gbogbo àṣẹ wa.
O ni to ba jẹ ifẹ Ọlọrun ni pe oun ni yoo di aarẹ lọdun to n bọ, ko si Yẹkinni ti yoo yẹ ẹ.

Leave a Reply