Ọdaran di meji, wọn ti mu wọda to tu adigunjale meji silẹ ni sẹẹli

Monisọla Saka

Lẹyin ti wọn fun un ni abẹtẹlẹ miliọnu kan Naira, wọda kan to n ṣiṣẹ lọgba ẹwọn Kirikiri, nipinlẹ Eko, Kayọde Fatombi, ti tu awọn adigunjale meji ti wọn n ṣẹwọn lọwọ silẹ, ṣugbọn ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ pada tẹ ẹ lori iwa ọdaran to hu ọhun.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ṣe sọ, niṣe ni wọda naa ṣe bii pe oun n ko awọn ẹlẹwọn mejeeji jade lọ sibi kan, bo ṣe ko wọn jade tan ni awọn ọdaran mejeeji fẹsẹ fẹ ẹ, wọn sa lọ.

Lẹyin tawọn ọlọpaa tọpasẹ wọn, ti wọn si fi panpẹ ofin gbe wọn, ni wọn jẹwọ pe owo lawọn san fun wọda tawọn fi ribi sa lọ.

Gẹgẹ bi ẹnikan to ṣalaye ọrọ naa fun akọroyin Punch ṣe sọ, o ni, “Ọgba ẹwọn Kirikiri, nipinlẹ Eko, ni ọkunrin naa ti n ṣiṣẹ. Ohun to ṣe ni pe, o mu awọn ẹlẹwọn meji kan ti wọn n jẹjọ lọwọ fun ẹsun ijinigbe ati idigunjale sa kuro latimọle. Irọ to pa ni pe niṣe lawọn mejeeji sa lọ lasiko toun n ko wọn jade lọ. Amọ to jẹ pe aṣiri pada tu lasiko iwadii pe oun lo mọ-ọn-mọ tu wọn silẹ pe ki wọn maa lọ.

“Lẹyin tawọn ọlọpaa tọpinpin awọn ọdaran naa, ti wọn si mu wọn tan, ni wọn jẹwọ pe owo lawọn fun un to fi dọgbọn ṣi awọn silẹ, ati pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500,000) ni ẹni kọọkan awọn fun un gẹgẹ bii owo iṣẹ to fẹẹ ṣe fawọn.

Wọn ti mu ọkunrin wọda yii, o si ti wa lẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko.

Lọjọ ti wọn maa gbe Fatombi wa sibẹ, niṣe ni wọn ko ma-mu-gaari si i lọwọ, ti wọn si tun ko galagala si i lẹsẹ lọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun yii.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun yii, ni wọn ni wọn yoo foju ẹ bale-ẹjọ”.

Leave a Reply