Adewale Adeoye
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ti tẹ awọn ọdaran meji kan, Abubarkar Haruna, ẹni ọdun mẹtalelogun, ati Ibrahim Sani, ẹni ọdun mejilelogun. ti wọn maa n fi gbogbo igba ja awọn olugbe agbegbe Tsohuwar-Tasha, nipinlẹ ọhun lole.
ALAROYE gbọ pe l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lọwọ palaba awọn ole ọhun segi, ti wọn si ri meji mu lara awọn to lọọ ja oniṣowo foonu igbalode kan lole ni ṣọọbu rẹ to wa lagbegbe ọhun.
Foonu igbalode bii aadọta lawọn ọlopaa gba pada lọwọ awọn ole naa lẹyin tọwọ tẹ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, CSP Gambo Isah, to ṣafihan awọn ọdaran mejeeji ọhun fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe ọjọ pẹ tawọn ọdaran naa ti n yọ awọn ọlọja agbegbe ọhun lẹnu, ko too di pe ọwọ tẹ wọn bayii.
O fi kun un pe awọn ọdaran naa pọ ju bayii lọ, ṣugbọn awọn kan lara wọn ti sa lọ, awọn si ti n ṣiṣẹ labẹnu lati ri wọn mu.
Alukoro ni, ‘‘Gbara ta a ba ti ri wọn mu la maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn.
‘‘Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ko ni i faaye gba iwa ọdaran tabi awọn janduku rara, iba dara bawọn ẹni ti iṣẹ ọwọ wọn ko mọ rara yaa tete filu naa silẹ ni kia, ko too di pe ọwọ ofin tẹ wọn’’.