Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ṣakiru Ọdunayọ ko baayan ja, jẹẹjẹ ẹ lo n lọ sibi to ti fẹẹ lọọ gbaṣẹ ti ẹnikan ni ko waa ba oun ṣe lagbegbe Sabo, ni Ṣagamu, nibi to ti n lọ naa ni ibọn ti ba a lori lasiko tawọn OPC atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ n bara wọn fa wahala lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, ẹsẹkẹsẹ naa lo si ti dagbere faye.
Ohun ti AKEDE AGBAYE gbọ ni pe lati ọjọ Aje, Mọnde, ni awọn OPC atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti n ba ara wọn ja, ohun ti wọn si lo fa ija ọhun ko se lori tikẹẹti ti awọn yuniọn onimọto ero n ja.
A gbọ pe awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Oodua pọ ninu awọn onimọto lagbegbe Sabo yii, bo ṣe waa kan awọn Ẹyẹ ni ko yeeyan. Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ Iṣẹgun to kọja yii, ọmọ ẹgbẹ OPC meji lo dagbere faye latari bawọn atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe fija pẹẹta.
Ṣakiru Ọdunayọ, baale ile to n ṣiṣẹ awọn to n tun redio ati tẹlifiṣan ṣe lo ṣikẹta awọn to ku naa. Bẹẹ, oun ki i ṣe OPC, bẹẹ ni ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun pẹlu.
Ọrẹ oloogbe yii kan to ba AKEDE AGBAYE sọrọ ṣalaye pe Ṣakiru Ọduayọ ṣi wa sọdọ oun lọjọ Mọnde, awọn jọ ṣere titi dọwọ alẹ to kuro lọdọ oun ni. Ọkunrin naa sọ pe ẹnikan lo ni ko waa ba oun ṣiṣẹ kan lagbegbe Sabo, to fi n lọ sibẹ lọjọ Iṣẹgun naa, ko too di pe o kagbako aṣita ibọn to ba a lori, to si ṣe bẹẹ ku lẹsẹkẹsẹ.
Oloogbe Ọduayọ ṣi ni iya laye, bẹẹ lo ni iyawo atawọn ọmọ to jẹ oun naa lo n gbọ bukaata wọn ki iku ojiji too wọle de. Bo si tilẹ jẹ pe alaafia ti pada sagbegbe naa lẹyin iṣẹlẹ to mu kaluku fori pamọ sinu ile rẹ, sibẹ, awọn ti ọfọ ṣẹ ṣi wa ninu ibanujẹ, iyẹn idile awọn OPC meji to ku ati ti Ṣakiru Ọdunayọ ti aṣita ibọn pa.