Ọdọọdun ni Tinubu ni ka maa gbaayan ṣiṣẹ ọlọpaa bayii-Ẹgbẹtokun  

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọga agba patapata ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa, Kayọde Ẹgbẹtokun, ti ni oun ti gbaradi lati mu atunto ọtun ba ileeṣẹ ọlọpaa jake-jado orile-ede yii, lati le maa gbogun ti oniruuru iwa ọdaran.

Ẹgbẹtokun sọrọ yii niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, lasiko abẹwo ọlọjọ kan to ṣe siluu Ilọrin, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla yii.

Nnkan bii aago mejila ọsan kọja iṣẹju diẹ leto naa waye lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa. Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa, CP Victor Olaiya, lo ṣafihan ọga agba awọn agbofinro ọhun, to si ki i kaabọ siluu Ilọrin. Ninu ọrọ rẹ lo ti ni igba akọkọ ti Ẹgbẹtokun, yoo wa siluu Ilọrin latigba to ti di ọga patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria niyi.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lasiko to ṣe abẹwo naa, Ẹgbẹtokun ni: “Mo ki ẹyin ọlọpaa nipinlẹ Kwara ku iṣẹ takuntakun, gbogbo awọn iṣẹ tẹ ẹ n ṣe ni mo n ri, gbogbo awọn ọdaran tọwọ yin n tẹ ni mo n ri patapata Ọlọrun yoo tubọ maa fun yin ṣe.

“Afojusun mi gẹgẹ bii ọga ọlọpaa ni lati ri i daju pe atunto de ba iṣẹ ọlọpaa, ti wọn yoo maa ṣiṣẹ wọn pẹlu imọ ijinlẹ, ti wọn o le maa fọwọ sọya ni gbangba pe ọlọpaa ni mi, iṣẹ ọlọpaa ni mo n ṣe. Ma a peṣe gbogbo awọn ohun ti ẹ nilo fun yin, a gbọdọ fagbara kun agbara yin nipa fifun yin lawọn irinṣẹ ti yoo mu iṣẹ yin rọrun, mo ṣakiyesi pe ẹyin ọlọpaa to n ṣiṣẹ lawọn ipinlẹ kere pupọ, ṣugbọn Aarẹ Bọla Tinubu ti buwọ lu u ka maa gba awọn eeyan ṣiṣẹ ọlọpaa lọdọọdun, eyi ti ko ni i jẹ ki iṣẹ wọ yin lọrun. A maa ṣe agbakalẹ eto kan ti wọn yoo ti maa ṣe idanilẹkọọ (Traning) fun awọn ọlọpaa lọdọọdun. Ma a sa gbogbo agbara mi lati mu igbelarugẹ ba igbaye-gbadun yin, ṣugbọn ki i ṣe afikun owo oṣu nikan ni eyi le gba waye, oniruuru ọna ni a le gbe e gba tawọn ọlọpaa yoo fi maa rẹrin-in lẹnu iṣẹ wọn, mo wa pẹlu yin lọjọkọjọ.

Ẹgbẹtokun, ni lẹyin tawọn ba ti ṣe awọn atunto to yẹ, awọn ọlọpaa yoo le maa gbogun ti awọn ọdaran atawọn ọta orile-ede Naijiria pẹlu irọrun.

Leave a Reply