Ọdun kan iṣakoso ijọba Tinubu, ifasẹyin nla gbaa lo mu ba awọn eeyan orileede yii – Bugaje

Adewale Adeoye

Ọkan pataki lara awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja tẹlẹ, Ọnarebu Usman Baguje, ti bẹnu atẹ lu iṣakoso olori orileede Naijiria, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, pe ifasẹyin nla gbaa ti ko lafiwe rara lo sọ orileede yii si,  dipo ko ṣatunse si i.

O ni kaka ki Aarẹ Tinubu yanju awọn oke iṣoro orileede yii to ba nilẹ, ṣe lo tun da kun un  laarin ọdun kan to gbajọba.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, ni Ọnarebu Usman sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n fesi si ibeere awọn oniroyin ileeṣẹ tẹlifiṣan Channel TV.

O ni, ‘Ẹ ma jẹ ki n tan yin tabi ki n fi dudu pe funfun fun yin, ijọba Aarẹ Tinubu ko ri oke iṣoro kan ṣoṣo yanju lati nnkan bii ọdun kan to ti gbakoso ijọba orileede yii lọwọ aarẹ ana. Eyi ti iba fi yanju awọn oke iṣoro kọọkan to n doju kọ awọn araalu lorileede yii, niṣe nijọba rẹ tun n da kun un. O ṣapejuwe iṣakoso Tinubu gẹgẹ bii eyi ti ko mọ nnkan to n ṣe rara.

‘‘O ṣe mi laaanu pe awọn ọmọ Naijiria ko lohun ti wọn fi le ṣe odiwọn iṣẹ idagbasoke ti awọn alaṣẹ ijọba wọn n ṣe nipo ti wọn yan wọn si, ṣe lo yẹ ki wọn kan an nipa fun  Tinubu pe ko waa tọka si iṣẹ idagbasoke kan pato to ti gbe ṣe laarin ọdun kan to ti wa nipo aṣẹ. Fawọn araalu atawọn to n ṣejọba le lori, iṣakoso ijọba Aarẹ Tinubu fun ọdun kan jẹ abamọ nla gbaa, ifasẹyin to mu ba wọn ko lafiwe rara. Olori orileede yii atawọn alabaṣiṣẹ-pọ rẹ ko le tọka si iṣẹ idagbasoke kan pato ti wọn gbe se laarin ọdun kan ti wọn gbajọba orileede yii. Iya nla ni wọn fi n jẹ awọn araalu pẹlu awọn eto iṣejọba wọn. ‘’Igbesẹ akọkọ ti wọn gbe ni gbara ti wọn gbajọba orileede yii ko bojumu rara, baṣubaṣu ni wọn si n ṣe ninu okunkun biribiri ti wọn ko ara wọn si. Asiko ree to yẹ kawọn alaṣẹ ijọba orileede yii gba pe awọn ko loye nipa iṣejọba ilẹ yii rara, ki wọn si bẹbẹ fun iranlọwọ awọn ọmọ orileede yii to jẹ ọlọpọlọ pipe, lati waa ran wọn lọwọ. Ọlọrun fun awọn ọmọ  Naijiria kọọkan lọpọlọ daadaa, wọn le ma jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa pẹlu Aarẹ Tinubu, koda, wọn le ma si ninu oṣelu orileede yii rara, bawọn orileede gidi lagbaaye ṣe n ṣe niyi. Wọn aa bẹbẹ pe, ki ọmọ ilẹ wọn waa ran ijọba lọwọ lati yanju oke iṣoro orileede wọn. ‘’Pe orileede wa n la oke iṣoro kọja ki i ṣe tuntun rara, aimọye orileede lagbaaye lo n la oke iṣoro tiwọn naa kọja daadaa, ṣugbọn bawọn ṣe n yanju iṣoro tiwọn ni pe wọn aa ranṣẹ pe awọn ọlọpọlọ pipe ilẹ wọn lati waa ran wọn lọwọ ni.

‘’Fun apẹẹrẹ, eto aabo lorileede yii mẹ-hẹ gidi, nigba tawọn agbebọn ba n ji awọn araalu gbe niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa, nibi tawọn olu ileeṣẹ ọlọpaa wa, nibi tawọn alagbara gbogbo wa, ki waa ni kawọn araalu nipinlẹ bii: Eko, Ogun, Ọṣun, Katsina, Zamfara ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣe o’’. Bẹẹ ni Bugaje sọ.

Leave a Reply