Faith Adebọla, Eko
Abamọ nla lọrọ da fun Ọgbẹni Taiwo Abiọla Adebọwale yii o, ọdun kan pere lo ku ko kẹkọọ-yege ni Fasiti Ladoke Akintọla to ti n kawe, ṣugbọn ikẹkọọ naa ti fori ṣanpọn bayii, ọgba ẹwọn nile-ẹjọ ni ko ti maa lọọ kọ ẹkọ tuntun pẹlu inira bayii, ọdun kan gbako lo si maa fi wa nibẹ.
Adajọ Oluwatoyin A. Taiwo tile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe, to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lo gbe idajọ rẹ kalẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, lori ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan an. Wọn lo lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara
Ọgbẹni Wilson Uwajuren, to jẹ Alukoro fun ajọ EFCC lo jẹ ka gbọ nipa iṣẹlẹ yii, o ṣalaye pe ipele karun-un ni afurasi ọdaran naa wa ninu ẹkọ rẹ ni Fasiti LAUTECH, Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn bo ṣe n kawe lo tun n ṣe jibiti lẹgbẹẹ kan, jibiti naa lo si ran an lẹwọn yii.
O ni Brownstone Estate, to wa ni Ikate, lagbegbe Ẹlẹgushi, ni Lẹkki, nipinlẹ Eko, lọkunrin naa n gbe, ibẹ lo ti n pe ara ẹ ni ọmọ Amẹrika fawọn to n lu ni jibiti, oun ti ṣiṣẹ ologun ri, ṣọja loun, pe Burton J. Smith lorukọ oun, ọmọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa nigba kan, Musiliu Smith, loun, bẹẹ lo ṣe fẹtan gba ẹgbẹrun lọna marunlelọgọrun-un o din ẹẹdẹgbẹta dọla ($104,500) lọwọ Corteny Selina Kaye, o loun maa ba tọhun ṣe okoowo owo-ori atẹ ayelujara kan ti wọn n pe ni Bitcoin, ṣugbọn alọ owo ni Kaye ri, ko ri abọ ẹ mọ.
Iwe ẹsun ti wọn fi kan afurasi naa ka pe: “Iwọ Adebọwale Taiwo Abiọla, laarin ọdun 2020, niluu Eko, o fẹtan ko awọn akọsilẹ irọ kan jọ, o si mọ lọkan ara rẹ pe jibiti lo fẹẹ fi awọn akọsilẹ naa lu, o si tun bura eke.”
Wọn bi i pe ṣe o jẹbi ati ko jẹbi, o loun jẹbi, kile-ẹjọ ṣiju aanu wo oun.
Adajọ Taiwo ni ọrọ naa ko gba ariwo mọ, o paṣẹ ki wọn gbẹsẹ le miliọnu marun-un naira ti wọn ba ninu akaunti Taiwo, ki wọn tun gbẹsẹ le ọkọ ayọkẹlẹ bọginni Mercedes Benz GLK to ni nọmba AKD 573 GK lara, ki wọn ta gbogbo dukia wọnyi, ki wọn si fi san owo olowo to ṣe gbaju-ẹ fun pada folowo. Adajọ ni ti owo naa ko ba ka gbese to jẹ, ki wọn bẹrẹ si i fa gbogbo dukia to ni ta lọkọọkan titi ti miliọnu mẹtadinlogun naira ti wọn lo lu jibiti ẹ maa fi pe.
Ki wọn si tun la a mẹwọn fọdun kan gẹgẹ bii ijiya ẹṣẹ ẹ, tabi ko sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, iyẹn to ba ti kọkọ san gbese ọrun ẹ tan.