Ọdun Ọlọjọ: Asiko ti to fun awa ọmọ ilẹ Afrika lati wa ni iṣọkan- Bonge 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọba kan lati orileede South Africa, Rabagaye Bonge, ti sọ pe aisi iṣọkan laarin awọn ọmọ ilẹ Afrika lo fa a ti awọn ọta ṣe n fi ogun ẹyin ja wọn.

Nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ to waye ni aafin Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, lọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni ori-ade naa ti sọ pe iyapa ti pọ ju ninu ẹya Afrika, eleyii to si n ṣakoba pupọ fun iran naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ohun to fa wahala iyapa naa ko ye ẹnikẹni, o si ti to asiko bayii lati ri i pe iṣọkan ati ifẹ pada, idi si niyi ti gbogbo orileede to wa labẹ ajọ Sovereign Congress of Africa fi gbọdọ ṣiṣẹ papọ.

“A gbọdọ ri i daju pe gbogbo Afrika wa niṣọkan. Ninu iṣọkan la ti le duro, iyapa ko le so eeso rere kan fun wa. A gbọdọ daabo bo ogun-ibi wa, eyi ti i ṣe oniruuru aṣa iyebiye ti a ni.

“A ko gbọdọ ba ara wa ja mọ. Ọkan naa ni wa. Ti a ba wa niṣọkan, awọn ọta maa bẹru wa. A gbọdọ pada si orirun wa, igba yẹn ni a maa bori aye.”

Ọba yii rọ gbogbo awọn ọmọ Afrika lati bọwọ fun ara wọn, ki wọn si maa fi ifẹ ṣe ohun ti wọn ba n ṣe.

Ninu ọrọ tirẹ, Kọmiṣanna fun ọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ọṣun, Dokita Biyi Ọdunlade, sọ pe pataki Ọlọjọ ni lati ṣapọnle aṣa Yoruba.

O ni ọdun naa jẹ ọkan lara awọn ọdun pataki ti ko jẹ ki aṣa, ede ati iṣe Yoruba parun. O si rọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba lati ri i daju pe aṣa wọn ko parun.

Leave a Reply