Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọsẹ to kọja yii niroyin gbode nipa Ọdunlade Adekọla, agba oṣere Yoruba to da ileewe ẹkọṣẹ tiata to pe ni OAFP silẹ. Ikilọ lawọn to gbe iroyin naa jade ṣe fun Ọdun, wọn ni ko yee ko ibasun bo awọn obinrin onitiata nitori ki wọn le di gbajumọ oṣere, wọn lo pẹ to ti n ṣe bẹẹ, asiko ti to wayii to gbọdọ wa egbo dẹkun fun iṣẹkuṣe.
Awọn to gbe iroyin naa jade ṣalaye pe ilakulaa ni Ọdun la Ẹniọla Ajao, wọn ni bẹẹ lo ṣe fun Taiwo Aromokun, Bukọla Adeẹyọ atawọn oṣerebinrin mi-in ti wọn gba abẹ rẹ kọja nidii iṣẹ tiata yii. Bẹẹ ni wọn ni ọmọ kan to n jẹ Nikẹ Hamzat to ṣẹṣẹ n goke agba nidii iṣẹ tiata ni Ọdun tun n fọ lẹnu bayii.
Wọn ni ohun ti Ọdun maa n sọ fun wọn ni pe ko si bi wọn ṣe le di sitaa, irawọ oṣere, boun ko ba tu wọn laṣọ wo, nitori oun ko ni i fun wọn niṣẹ ṣe. Bi aye ko ba si maa ri oju wọn ninu awọn fiimu, ko si bi wọn yoo ṣe di gbajumọ oṣere, wọn ko ni i buloo (blow) bii aṣa awọn eeyan.
Kia ni iroyin naa tan kalẹ, to gbilẹ bii olu-ọran, awọn eeyan kan si ti bẹrẹ si i da oṣere-kunrin to ga daadaa naa lẹbi, wọn ni bi awọn to n sọ bẹẹ ko ba ri, wọn ko ni i sọ.
Ohun to mu Ọdun ọmọ Adekọla ṣe fidio kan ree, nibi to ti ṣalaye ara ẹ lori ayelujara ki gbogbo aye le ri i. O tilẹ loun ko fẹẹ sọrọ tẹlẹ, nitori ki i ṣe gbogbo ohun ti wọn ba n sọ nipa eeyan leeyan gbọdọ fesi si. O ni awọn eeyan kaakiri agbaye ni wọn n pe oun pe koun fesi, ohun to jẹ koun ṣalaye ree, nitori ọjọ iwaju.
Ọdun sọ pe, “ Wọn ni mo maa n beere fun ibalopọ ki n too fun ẹnikẹni ni ipa to maa ko ninu ere nileewe mi, OAFP, emi Ọdunlade ọmọ Seriki Babalogun, ni mo ṣẹṣẹ maa waa ni kọmọ kan gbe idi wa, ko too di pe mo fun un ni ‘role’
“Ẹ beere lọwọ Nikẹ, Ẹniọla Ajao, Taiwo Aromokun atawọn oṣerebinrin mi-in to wa ninu ẹgbẹ mi boya mo beere ibalopọ lọwọ wọn ki n too fun wọn ni ipa ti wọn maa ko ninu ere ri. Emi.
“Mo n sọ eleyii bayii, mo dẹ n pe gbogbo obinrin to ti gba ọdọ mi kọja, Ọlọrun lo n sọ eeyan di sitaa, ṣugbọn lati ori Taiwo Aromokun, Ẹniọla Ajao, Tosin, Nikẹ Hamzat, Biọla Adekunle, Buki Adeẹyọ, ki wọn jade waa sọ ọ bayii to ba jẹ pe mo bi ẹ leere ri pe gbe abẹ ẹ wa ki n too fun ẹ ni role. To o ba bo mi, Ọlọrun o ni i bo ẹ.
“Ẹ kan jade kẹ ẹ waa sọ ọ si abẹ fidio yii, ẹnikẹni ninu yin ti mo ba ti ba sọ ọ ri ninu ẹyin tẹ ẹ wa ni OAFP. Mo gbọdọ ṣalaye yii nitori awọn ọmọde ti wọn nifẹẹ siṣẹ tiata yii, paapaa awọn obinrin, ti wọn n wo wa bii awokọṣe”
O tẹsiwaju pe ọdun 1996 loun ti bẹrẹ iṣẹ tiata, toun ti n ṣiṣẹ koun le lokiki ati orukọ rere, awọn kan yoo waa jokoo sibi kan, wọn yoo fẹẹ ba orukọ naa jẹ nitori ohun ti wọn fẹẹ jẹ. O ni ki wọn ṣe e siwaju, ki wọn ma ba oun dan iru ẹ wo.
Lọwọ ipari fidio naa lo ti fepe bọnu fawọn to ni o n fẹ oṣere kan ti wọn n pe Nikẹ Hamzat. O ni bi wọn ko ba mu ẹri wa pe oun n ba Nikẹ sun, ibinu Ọlọrun Ọba ni wọn yoo maa ri.
Ọdun ni Ọlọrun a ba wọn wi, afi bi ko ba si Ọlọrun mọ lo ku. Ọdun ni awọn eeyan to wa nileewe oun bayii to mẹẹẹdọgbọn, tọkunrin tobinrin, ṣe oun ni ki ọkunrin naa gbedii wa ni. O ni meloo labẹ ọhun gan-an, awọn ti wọn ni Nikẹ waa ba iyawo oun ja, o waa bu u nile, ninu ile wo, nibo ni iru ẹ ti ṣẹlẹ, ko si aaye radarada.
Nigba to sọrọ yii de ibi yii, iyawo rẹ naa fara han ninu fidio yii lati kin ọkọ ẹ lẹyin.
Ṣugbọn ko pẹ lẹyin ti fidio ọdun jade ti akọroyin ayelujara kan, Kẹmi Filani, to fẹsun kan Ọdun fi gbe iroyin mi-in jade lati sọ pe irọ ni Ọdun n pa.
Kẹmi Filani kọ ọ pe, ‘‘Opurọ pasitọ, irọ pọ, o ti pọ rẹpẹtẹ, opurọ olufẹ. Gbogbo ẹyin tẹ ẹ n ṣi abẹ yin fun un, tẹ ẹ n jẹ ko maa ka itan yin soke, ẹ wo bi wọn ṣe lawọn o mọ ‘kinni’ yin ri nigboro, ti wọn lawọn o mọ yin ri. O ma ṣe fidio rẹ yẹn daadaa o, ṣaa sinmi iranu yẹn, SINMI Ẹ”
Bẹẹ ni akọroyin naa tun gbena woju Ọdun lẹyin fidio ti oṣẹre naa ju sita.
Ṣaa, ọrọ ọhun ṣi maa lẹyin bawọn eeyan ṣe n wi, wọn ni laarin awọn akọroyin yii ati Ọdun ọmọ Adekọla, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, nitori o da bii pe ẹni kan ninu wọn lo n purọ, ti ẹni kan si n sọ ootọ.