Ofin ko faaye gba ẹnikẹni lati lu ọlọpaa nita gbangba pẹlu aṣọ ijọba lorun-Adejọbi

Adewale Adeoye

‘Ki i ṣohun to ba ofin ilẹ wa mu rara pe kawọn araalu maa yọwọ ẹṣẹ tabi ki wọn maa tabuku ọlọpaa to n ṣiṣẹ sin ilu lọwọ. Beeyan kan ba yẹpẹrẹ ọlọpaa nita gbangba, ẹlẹgbẹ pe onitọhun n yẹpẹrẹ orileede yii niyẹn, ofin si fajuro si eyi patapata, ti ijiya si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ labẹ ofin ilẹ yii’

Eyi ni ọrọ to jade lẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii, Ọgbẹni Muyiwa Adejọbi, lakooko to n ba awọn oniroyin kan sọrọ niluu Abuja lori bawọn araalu kọọkan ṣe n gbeja koju awọn ọlọpaa ilẹ wa nigba gbogbo bayii.

Alukoro ọhun ni apẹẹrẹ ọwọ ati aṣẹ orileede yii ni awọn ọlọpaa jẹ nigba gbogbo, ko si yẹ rara lati maa yẹpẹrẹ wọn nita gbangba, koda bi wọn ba ṣohun ti ko daa fawọn araalu nita gbangba, ofin ko sọ pe kawọn araalu maa lu wọn nita gbangba gẹgẹ bo ti ṣe n waye lọpọ igba bayii.

O ni ṣe lo yẹ ki wọn fọrọ wọn ṣe pe ‘Beegun ba ṣeere, bo ṣebi, a n fi ọwọ igbalẹ ji i ni’, Ki wọn lọọ fọrọ wọn to awọn alaṣẹ ijọba to gba wọn sẹnu iṣẹ leti lo daa julọ.

Ṣa o, Adejọbi ni nigba kọọkan, o ṣe pataki fawọn ọlọpaa ọhun lati maa lo ọwọ lile diẹ lati maa fi mu awọn ọdaran kọọkan ti wọn ko fẹẹ gboju-bọrọ lakooko ti wọn fẹẹ fọwọ ofin mu wọn fohun aburu ti wọn ṣe lawujọ.

O ni, ‘Bi ọlọpaa kan ba ṣiwa-hu lawujọ wa tabi nita gbangba, ofin ilẹ wa ko sọ pe k’araalu doju ija kọ ọlọpaa bẹẹ rara nita gbangba, ofin ilẹ wa fajuro si eyi patapata, paapaa ju lọ, bi ọlọpaa naa ba wọ aṣọ ijọba sọrun. Apẹẹrẹ rẹ ni ti ọlọpaa kan bayii ti mo ri fidio oniṣẹju diẹ kan lori ẹrọ ayelujara laipẹ yii, nibi ti ọlọpaa ọhun ti n lu ọlọkada kan lakooko to fẹẹ gba ọkada ọwọ rẹ, loootọ ọlọkada naa ti ṣẹ sofin ipinlẹ Eko, to si yẹ ki wọn gba ọkada to n gun naa nidii rẹ, ṣugbọn bi ọlọpaa naa ṣe n lu u yẹn ki i ṣohun to daa rara, ki i ṣe ba a ti ṣe kọ wọn lo ṣe n huwa yẹn rara. Nigba ti mo wo fidio yẹn daadaa, mo ri i pe, ki i ṣe kondo ti awọn ọlọpaa maa n lo lo fi n lu ọlọkada yii, o lu u debii pe ẹjẹ n jade lara rẹ naa ni, nigba to ri i pe awọn ero iworan to wa nitosi fẹẹ gbeja ọlọkada naa lo ba sa lọ patapata pẹlu Kẹkẹ Marwa kan bayii to wa nitosi rẹ.

Leave a Reply