Jide Alabi
Niwaju igbimọ to n gbọ ẹsun lori bi awọn ṣọja ṣe kọ lu awọn ọdọ to n ṣewọde SARS, logunjọ, oṣu kẹwaa yii, nipinlẹ Eko ni Olori ikọ ọwọ kọkanlelọgọrin awọn ọmọ ogun ọtelẹmuyẹ ninu iṣẹ ṣọja to wa niluu Eko, Brigedia Ahmed Taiwo, ti fidi ẹ mulẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, pe mọto meje tawọn ṣọja kun inu ẹ bamu ni wọn ko lọọ ka awọn ọdọ mọ too-geeti Lẹkki, bẹẹ ni awọn ṣọja ko ọta ibọn lọ sibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ki i ṣe pe wọn yin in mọ awọn to n ṣewọde naa. Wọn ko o dani lati le fi daabo bo awọn ọmọ ogun to lọ sibi iṣẹlẹ naa nitori a ki i ṣe e mọ, awọn kan le fẹẹ kọju ija si wọn ni.
O fi kun un ki i ṣe pe ọta ibọn yii ni awọn ṣọja yii yin mọ awọn to n ṣewọde ni Lẹkki, bi ko ṣe ọta ibọn oni rọba ti ko le ṣe eeyan leṣẹ.
Fidio kan ti wọn wo niwaju igbimọ ọhun lo fidi ọrọ yii mulẹ ni Satide, ọjọ Abamẹta.
Ninu fidio ọhun gan-an ni wọn ti ri i pe ko si hilahilo kankan lagbegbe naa latigba tawọn ọdọ ọhun ti wa nibẹ ti wọn n ṣe iwọde wọn jẹẹje, ṣugbọn lojiji lọrọ di bo o lọ yago, ti wahala de nigba ti awọn ṣọja ya de bii ẹni waa kogun jalu.
Ohun ti wọn kiyesi ninu fidio ọhun ni pe ni deede aago meje ku iṣẹju mẹtadinlogun lọrọ daru lojiji, tawọn eeyan bẹrẹ si i sare lẹlẹ lọ si too-geeti lati ileetura Oriental Hotel, to wa nitosi ibẹ.
Ṣiwaju si i, fidio ọhun tun ṣafihan pe nigba ti aago meje ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni ọkọ awọn ṣọja meje yọ lọọọkan, tawọn ṣọja si kun inu ẹ fọọfọ.
Bẹẹ ni ko ju iṣẹju mẹwaa lọ ti awọn ṣọja de ni wọn pana to maa n tan yan-an ni too-geeti Lẹkki yii, ti gbogbo agbegbe naa si wa ninu okunkun birimubirimu.
Ninu fidio ọhun naa ni igbimọ naa ti ri i pe ni nnkan bii aago meje ku iṣẹju marun-un, ni ọkan ninu awọn mọto to ko awọn ologun ọhun wa kọja lọ si odi keji nibi ti awọn to n ṣewode pọ si i.
Tẹ o ba gbagbe, oriṣiiriṣii awuyewuye lo ti tidi ọrọ awọn ṣọja ti wọn lọọ ka awọn ọdọ mọ too-geeti Lẹkki, l’Ekoo, ṣugbọn pẹlu fidio ti wọn tun n lo nibi iwadii igbimọ yii!