Monisọla Saka
Ọjọgbọn Muhammed Mustapha Akanbi ti i ṣe Giiwa keji ileewe giga Fasiti ipinlẹ Kwara (KWASU), ti dagbere faye lọjọ Aiku, Sannde, ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lẹni ọdun mọkanlelaaadọta(51) niluu Dubai, lorilẹ-ede United Arab Emirates (UAE) lo dakẹ si latari aisan to ti n ba a finra lati ọjọ pipẹ.
Ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun 2020, lo gba ipo adari fasiti ọhun lẹni ọdun mejilelogoji (49), lẹyin ti Ọjọgbọn Na’Allah fipo ọhun silẹ fun un lọ si Fasiti ilu Abuja, eyi lo si mu ko jẹ ọga agba ileewe giga fasiti tọjọ ori rẹ kere ju lọ nilẹ Naijiria.
Ọdun 2012 ni oloogbe yii gboye ọjọgbọn lẹni ogoji ọdun. Ko too depo adari naa, olukọ imọ ofin nipa okoowo ni (Business Law) Ọjọgbọn Mustapha nileewe giga Fasiti Ilọrin. Ọdun 1998, lo ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii olukọ kekere (assistant lecturer) lẹka imọ nipa ofin ni fasiti naa.
Ọmọ agboole Mọgaji Kemberi, Awodi, lagbegbe Gambari, niluu Ilọrin, ni Ọjọgbọn Mustapha. O kawe alakọọbẹrẹ rẹ kaakiri awọn ilu bii Kano, Port Harcourt, Ibadan ati Okigwe, nipinlẹ Imo. Lẹyin to pari ẹkọ rẹ ni Kings College ati Fasiti London lo pada wa sile lati kẹkọọ gbawe ẹri mo-yege nileewe ẹkọ imọ ofin (Nigerian Law School) ẹka ti Victoria Island, nipinlẹ Eko. Gbara to ṣetan nibẹ lọdun 1995 lo ta kọsọ si ile ifowopamọ apapọ ilẹ wa(Central Bank of Nigeria), lati sin ilẹ baba rẹ laarin ọdun 1995 si 1996.
Latari ipa ribiribi to ko lẹka imọ nipa ofin atawọn iṣẹ pataki mi-in ni wọn ṣe sọ ọ di agba lọọya (SAN), lọdun 2018.
Ọmọ bibi inu Justice Mustapha Akanbi ti i ṣe aarẹ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ilẹ wa (The Court of Appeal) tẹlẹ ni oloogbe yii.