Ọga agba ileeṣẹ ijọba ku sọfiisi rẹ n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Titi di asiko yii, ko ti i sẹni to mọ iru iku to pa dirẹkitọ ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ọgbin ati idagbasoke ẹsẹ kuku nipinlẹ Kwara, Dokita Khalid Ibrahim Ndaman, ẹni ti wọn ṣadeede ba oku rẹ ninu ọfiisi laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii nipa iku ọkunrin naa.

 

Ndaman to jẹ ọga agba lẹka to n mojuto itọju awọn ohun ọsin ati ẹranko (Veterinary) ni iku rẹ si n jẹ kayeefi fawọn eeyan.

Iwadii fi han pe ṣaka lara ọkunrin naa da lasiko to de ọfiisi rẹ laaarọ ọjọ Aje yii. Nigba ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ to wa labẹ rẹ lọọ ba a lati jiroro lori ọrọ to jọ mọ iṣẹ wọn lo ba a to gbe ori sori tabili rẹ bii ẹni sun.

Wọn ni iyẹn kan ilẹkun ọfiisi rẹ titi, ṣugbọn ko fesi, nigba to duro diẹ lo wọle. Iyẹn ki i, ṣugbọn ko dahun, lo ba sun mọ on lati fọwọ tọ ọ, ibẹ lo ti mọ pe ọkunrin naa ti jade laye, bo ṣe kegbajare sawọn eeyan niyẹn.

Alukoro ileeṣẹ nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni iwadii ti n lọ lori ẹ.

Leave a Reply