Ọga ajọ eleto idibo gbọdọ fipo silẹ, o ta ibo wa ni-Ẹgbẹ Labour

Monisọla Saka

Ọkan ninu awọn agbẹnusọ igbimọ eleto ipolongo ibo aarẹ fẹgbẹ oṣelu Labour Party, Kenneth Okwonkwo, to tun jẹ oṣere tiata ilẹ Ibo, ti pe fun iyọnipo ọga agba ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, lori ọna ti wọn lo gba ṣeto ibo aarẹ ati tawọn aṣofin to waye loṣu Keji, ọdun yii, ati esi ibo to kede, eyi ti wọn lo ni magomago ninu.

Okwonkwo fẹsun kan ajọ yii pe niṣe ni wọn ta ibo aarẹ ati tawọn aṣofin ọhun fẹni to kowo to pọ ju lọ silẹ, pẹlu bawọn ọmọ Naijiria ṣe kọ lati ta ibo wọn to, ti wọn si dibo fẹni to wu wọn.

Nigba to n fitara pe pe ki wọn yọ Yakubu nipo lori ẹrọ abẹyẹfo twitter ẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii. Oṣere yii beere idi ti ajọ naa fi sare kede ẹni to wọle, ati pe ohun fẹẹ mọ idi ti esi idibo ko ṣe ti i si lori ẹrọ ayelujara ileeṣẹ naa lẹyin bIi ọjọ mọkanla ti wọn ti pari eto idibo.

O tẹsiwaju pe niwọn igba ti ajọ INEC Ko ti i gbe gbogbo esi idibo Aarẹ ati tawọn aṣofin sori afẹfẹ yii, a jẹ pe eto idibo ko ti i pari niyẹn, nitori bẹẹ, wọn o ba ma ti kuku kede Aarẹ tuntun ti wọn lo jawe olubori ninu ibo naa.

O ni, “Awọn ọmọ Naijiria kọ lati ta ibo wọn, nitori bẹẹ ni wọn ṣe dibo fẹni to wu wọn. Ṣugbọn ajọ INEC ti ko ni ẹri ọkan pada ta ibo wọn fẹni to kowo to pọ ju lọ silẹ. Ko si nnkan kan to n ṣe awọn ọmọ Naijiria, iṣoro ta a ni ko ju aiṣododo atawọn adari ti wọn o gba muṣe lọ. A o gbọdọ faaye silẹ fun eto idibo Aarẹ ti wọn fẸẹ fi tu wa jẹ yii lati lọ bẹẹ.

“Ọkunrin ọga INEC ti wọn n pe ni Mahmood yẹn gbọdọ lọ ni. Mo fẹ ki ẹyin eeyan naa fẹnu si ọrọ yii, ẹ gbohun yin soke, lati le yi awujọ wa pada kuro ni ti tawọn ti wọn o ni laakaye. Ọjọ mọkanla ti re kọja lẹyin ti wọn dibo Aarẹ, wọn o si ti i gbe esi idibo sibẹ. Ohun to waa kan fun Mahmood ni lati lọọ kede ẹni to wọle aarẹ, pẹlu awuruju esi idibo ti wọn gbe kalẹ. O ma ṣe o!

Ẹ ma sọ ireti nu, iranlọwọ wa ko ni i pẹẹ de mọ. Mahmood ati awọn eleto idibo Eko ati ipinlẹ Rivers gbọdọ lọ ni. A ti fi igbagbọ wa sọwọ Ọlọrun”.

Lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, ti ajọ INEC ti kede Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bii aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, lẹyin ti wọn loun lo gbegba oroke ninu ibo ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ni awọn ojugba rẹ lẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour Party, Alaaji Atiku Abubakar ati Peter Obi, ti gba ile-ẹjọ lọ, kaluku wọn lawọn fẹẹ gba ẹtọ awọn pada, nitori ọmọ ọba ni ajọ INEC gbe f’Ọṣun Tinubu.

Leave a Reply