Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọga agba ọlọpaa lorileede Naijiria, Usman Alkali Baba, ti paṣẹ pe ki Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Ọlalẹyẹ Falẹyẹ, bẹrẹ iwadii lori wahala kan to bẹ silẹ laarin obinrin ọlọpaa kan ati ọga rẹ.
Insipẹkitọ ọlọpaa naa, Ọlọrunṣogo Bamidele, to n ṣiṣẹ ni Ọdẹ-Omu, nijọba ibilẹ Ayedaade, nipinlẹ Ọṣun, lo fẹsun kan ọga rẹ, DCO Ajayi Matthew, ninu fidio kan to ṣe jade, pe o ja oun sihooho, to si lu oun lalubami lọjọ Tusidee ọsẹ yii.
Ẹṣẹ to ni oun ṣe Ajayi ni pe o dẹnu ifẹ kọ oun, oun si sọ fun un pe oun ko le fẹ ẹ nitori iyawo ile loun, o ni latigba naa lo ti n parọ oriṣiiriṣii mọ oun nibi iṣẹ.
O ni nigba to di ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo bẹrẹ si i lu oun nilukulu, o ja oun sihooho, o si gbe ibọn pe oun yoo yin in lu oun.
Gẹgẹ bi Bamidele ṣe sọ, “Ki ni ẹṣẹ mi, o lu mi, o ṣe mi leṣe ni aya, apa, orukọ rẹ ni Ajayi Matthew. Nitori pe o ni ki emi ati oun maa jade, mo si sọ fun un pe iyawo ile ni mi, mi o le ṣe e, igba yẹn lo bẹrẹ si i ba mi lorukọ jẹ.
“O n sọ fawọn eeyan kaakiri pe emi ati oun n fẹra wa, eleyii bi mi ninu. Awọn kọnstebu meji atawọn araalu mẹwaa ni wọn wa nibẹ. O lọ sinu ile, o lọọ gbe ibọn, o loun yoo yin in lu mi, awọn ti wọn wa nibẹ sọ pe ki n maa sa lọ, ṣugbọn mo kọ jalẹ pe n ko ni i sa lọ.
“Ẹ gba mi lọwọ Ajayi o, o fẹẹ pa mi o”
Ni bayii, IGP Alkali, ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, Muyiwa Adejọbi, fi sita, sọ pe oun yoo maa reti abọ iwadii kọmiṣanna ọlọpaa lori iṣẹlẹ naa.
O fi da awọn araalu loju pe idajọ ododo yoo waye lori ọrọ naa.