Mo ti lẹni ti mo fẹẹ fẹ – Ẹniọla Ajao
Arẹwa ni, oju rẹ tun pawo pẹlu, bi wọn ba si n sọ pe ta lọmọ ti wọn n sọ lasiko yii lagboole tiata, Ẹniọla Ajao ni. Eyi tumọ si pe laarin awọn oṣẹrebinrin ilẹ Yoruba lonii, ṣaaṣa eeyan ni wọn yoo darukọ ọmọbinrin yii leti ẹ ti yoo ni oun ko mọ ẹni to n jẹ bẹẹ, gbajumọ oṣere gbaa ni.
Ibeji ni Ẹniọla, o kan jẹ pe ikeji rẹ ki i ṣe tiata ni, ileefowopamọ niyẹn wa to ti n ṣiṣẹ aje. Eyi atawọn nnkan mi-in ni Ẹniọla Ajao ba akọroyin AKEDE AGBAYE, ADEFUNKẸ ADEBIYI, sọ lọsẹ to kọja yii loko ere kan n’Imọta.
ẸNIỌLA AJAO: Orukọ mi ni Ẹniọla Ajao, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ni wọn bi emi ati ekeji mi (ibeji ni mi), siluu Ẹpẹ ti i ṣe ilu baba wa.
Ọmọ mẹfa lawọn obi wa bi, awa ibeji si ni abigbẹyin wọn. Mo lọ sileewe alakọọbẹrẹ Saint Micheal’s Anglican School, Ẹpẹ, ati Army Secondary School, toun naa wa l’Ẹpẹ. Lẹyin iyẹn ni mo lọ sileewe Gbogboniṣe Yaba College of Tecnology, mo kẹkọọ nipa iṣiro owo nibẹ fun ipele akọkọ ti wọn n pe ni ND. Mo ṣẹṣẹ waa lọ si Yunifasiti ipinlẹ Eko, nibi ti mo ti gba BSc ninu iṣiro owo kan naa.
BI MO ṢE BẸRẸ IṢẸ TIATA
Mo bẹrẹ iṣẹ tiata lọdun 2004, ọdun kẹrindinlogun sasiko yii. Ilu Eko yii naa ni mo ti bẹrẹ, latigba ti mo ti wa nileewe girama ni mo ti nifẹẹ si i, emi ni mo maa n ṣaaju ninu gbogbo ere ta a maa n ṣe nigba yẹn. Ṣugbọn mi o ro pe mo le fi ṣiṣẹ ṣe, afi nigba ti mo de Yaba Tech, ti mo pade ẹgbọn ọga ti mo kọṣẹ lọwọ ẹ, olootu fiimu lawọn, Adesanya Adeshina lorukọ wọn, ọdọ wọn ni mo ti maa n lọọ ṣe rihasa, ti a maa jo daadaa pẹlu awọn ẹkọ yooku.
Mo wa nibẹ fọdun meji, mo gbayọnda lọdọ wọn lọdun 2006. Loootọ lawọn eeyan maa n ro pe Ọgbẹni Ọdunlade Adekọla lo kọ mi niṣẹ, ọdọ wọn kọ ni mo ti bẹrẹ, bii pe keeyan pari yunifasiti nibi kan, ko waa lọọ ṣẹ Masita nibomi-in ni ẹkọ ti mo kọ lọdọ Ọdunlade Adekọla.
AWỌN ẸBI MI KO LODI SI TIATA TI MO DARAPỌ MỌ
Dadi mi mọ pe mi o ki i ṣe ọmọkọmọ, wọn mọ pe bi mo tiẹ n ṣe tiata, iyẹn ko ni ki ma kọju si ẹkọ mi. Wọn fẹ ki n kawe, ki n di onimọ iṣiro, mo dẹ ka a, ko di iwe mi lọwọ.
Nigba ti mo sọ fun wọn pe mo fẹẹ ṣe tiata, wọn kan sọ fun mi pe ki n ranti ọmọ ẹni ti mo n ṣe ni, wọn ko sọ pe ki n maa ṣe e. Wọn mọ pe mo tiẹ ti fẹẹ pari ẹkọ mi nigba ti mo ni mo fẹẹ maa ṣe tiata yẹn. Ikeji mi n ṣiṣẹ nileefowopamọ ni tiẹ, banka loun, o dẹ tun n ṣowo.
OJU TI RI KI N TOO DI GBAJUMỌ OṢERE
Ko yiisi rara o, oju ti ri oriṣiiriṣii nnkan ki n too di gbajumọ oṣere. Ẹni ti ko ba farabalẹ ninu iṣẹ wa yii, to kan ro pe oun le sare wọbẹ koun dẹ sare di gbajumọ, irọ lo pa.
Akọkọ ni pe keeyan kọkọ mọ nnkan to n ṣe, ko tẹnu ara ẹ wo ko mọ pe oun fẹẹ ṣiṣẹ yii, ko dẹ foju si i. Kikọ ni mimọ, ko sẹni to gbe e wa latọrun. Teeyan ba foju siṣẹ, owo maa de, orukọ maa de. Ṣugbọn teeyan ba n gbọn kiri, ti ko duro nibi kan, o kan maa maa sa kiri naa ni, ko le ri nnkan kan nidii iṣẹ yii.
LỌJỌ TI MO KỌKỌ DOJUKỌ KAMẸRA
Kamẹra lasan maa n dẹru baayan ti wọn ba gbe e seeyan loju fun igba akọkọ. Ẹru ba mi lọjọ ti mo kọkọ dojukọ kamẹra, ti wọn ni ki n maa sọrọ, ki wọn si maa ya mi.
Mo ranti pe ere ti mo kọkọ ṣe to gbe mi jade ni wọn pe ni ‘Igba aimọ, ọdun 2006 lo jade, emi dẹ ni mo ko ipa olubori (lead role) nibẹ.
Ni bayii, ere ti mo ti kopa ninu ẹ ti le ni marundinlọgọrin (75).
AWỌN TI WỌN N SỌ PE ỌRẸKUNRIN MI NI ỌDUNLADE ADEKỌLA
Mi o fẹẹ dahun ibeere yii tẹlẹ, mo fẹẹ sọ pe kẹ ẹ ma mẹnu lọ sibẹ ni, ṣugbọn ma a dahun.
Ọga mi ni Ọdunlade Adekọla, ko si nnkan mi-in mọ lẹyin iyẹn laarin emi pelu wọn.
Iyawo wọn (Iyawo Ọdunlade), bii ọrẹ mi ni wọn jẹ, bii ẹgbọn mi ni wọn jẹ. Ile wọn, bii ile mi naa ni, famili wọn, bii famili mi ni.
Nigba ti ọkan mi ba ti mọ pe ko si nnkan kan laarin wa, ariwo ọja leyi ti wọn n sọ kiri yẹn.
Ṣẹ ẹ ri rumọọsi, ara iṣẹ wa naa ni. Eeyan o le wa a ti ninu iṣẹ wa yii. Ẹni ti ko ba ti ni ara to fi maa gba awọn ọrọ bii eyi si, ko ni i de ibi kankan. Eeyan meloo ni mo fẹẹ maa sọ fun pe ko si nnkan kan laarin wa.
BI MO ṢE MANEEJI ASIKO KORONA
Ẹkọ nla ni Korona waa kọ wa, lo waa kọ gbogbo aye. Arun yẹn waa kọ wa pe Ọlọrun wa, omugọ eeyan lo maa ni Ọlọrun ko si.
Nigba teeyan ba wa laye lo n lọ soke sodo, to n ṣe wahala kiri. Ẹ wo bi Koro ṣe de ti gbogbo nnkan dawọ duro, to jẹ pe awọn eeyan ku lọ rẹpẹtẹ ni.
Ọlọrun n sọ fun wa pe Oun ni Ọlọrun, igba to ba wu Oun loun le dawọ ohun gbogbo duro, ti ko si sẹnikan ti yoo mu un si i. Gbogbo wahala ti a n ṣe kiri yii, nigba teeyan ṣi wa laye ni o, ti a ba ti ku, o tan, ohun aye aa baye lọ ni.
Korona waa kọ wa pe ka maa sin Ọlọrun ni o, nitori Ọlọrun le mu wa sọdọ nigba to ba wu u.
Bi mo ṣe maneenji ara mi ninu Korona, hmmm, o daa keeyan ni ajaṣẹku, ko daa keeyan maa fi ọwọ mẹwẹẹwa jẹun. Ajẹṣẹku ni mo fi gbera lasiko Koro, igba yẹn le gan-an, gbogbo eeyan lo kan. Awọn tiwọ fẹẹ lọọ ba fun iranlọwọ gan-an n maneeji ara wọn ni, nitori o kan awọn naa. A ṣaa dupẹ f’Ọlọrun ṣa, bo ṣe le to, Oluwa gba akoso.
BI MO ṢE MAA N SINMI
Mo maa n gba asiko isinmi ni, mo le gba ọsẹ kan tabi ọjọ mẹta, ma a sinmi, mi o ni i lọ sibi kankan. Mo kan maa wa nile ni ti mo ba ti ri i pe mo ti ṣiṣẹ mi de ibi to lapẹẹrẹ.
MO TI LỌKỌ AFẸSỌNA
Mo lẹni ti mo n fẹ, ọkọ afẹsọna mi. Lagbara Ọlọrun, gbogbo ẹ aa jọra wọn laipẹ.
OUNJẸ TI MO FẸRAN JU
Emi o lounjẹ kan pato ti mo fẹran, ka ṣaa ti ri nnkan fi sẹnu ni, mo wa ok ti mo ba ti ri nnkan fi sẹnu.