Monisọla Saka
A ki i fi iṣẹ igbọnsẹ ran ọmọ ẹni ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Idowu Owohunwa, fọrọ náà ṣe l”Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, pẹlu bo ṣe ṣabẹwo si ile ọlọkada kan tawọn ọlọpaa fiya jẹ. Niṣe ni wọn lu u daadaa, ti wọn sì tun kan irin kan mọ ọn lori. Niṣe ni ẹjẹ n da ṣoroṣoro lori ọmọkunrin naa.
Ninu fidio kan to n ja ran-in lori ayelujara nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, odun yii, lawọn agbofinro ti da ọlọkada naa duro, wọn fẹẹ gbe okada rẹ lọ nitori o ṣe lodi sofin ijọba Eko to ni ki wọn yee gbe ọkada kiri igboro.
Niṣe lawọn ọlọpaa to to bii mẹrin naa dawọ-jọ lu ọmọkunrin yii. Bi wọn ṣe n gba a leti ni wọn n kan kondo mọ ọn lori. Gbogbo bi wọn ṣe n na ọmọkunrin yii lo n jijadu ki wọn ma raaye gbe ọkada naa lọ, bẹẹ ni ọkan ninu awọn agbofinro yii n ti i danu.
Awọn ọlọpaa ko dawọ nina yii duro, pẹlu ibinu ni ọkan ninu wọn si fi la kinni kan bii irin bayii mọ ọlọkada naa lori. Oju-ẹsẹ ni ẹjẹ bo ọmọkunrin yii, ti aṣọ rẹ si rin gbindin fun ẹjẹ.
Asiko naa ẹni kan ninu wọn ta mọ ọkada naa, to n gbe e sa lọ, bẹẹ lawọn to ku ko sinu kẹkẹ Marwa kan, ni wọn ba lọ.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọkunrin yii tun gbiyanju ati le wọn ba, ko ṣee ṣe fun un. O ti ṣeṣe gidigidi, bẹẹ lo fowo di iwaju ori ti wọn kan nnkan mọ, ẹjẹ si n da ni koṣẹkoṣẹ.
Ninu ọrọ ẹ, Benjamin Hundeyin, ti i ṣe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, kọ ọ sori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ pe Owohunwa koro oju si nnkan tawọn agbofinro naa ṣe, ati pe wọn ti gbe igbesẹ ifiyajẹni lori iwa tawọn agbofinro naa hu.
O ni, “Lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa, lọọ ṣabẹwo si ọkunrin ti wọn fiya jẹ naa atawọn aṣaaju pẹlu ọmọ ẹgbẹ adugbo awọn ẹya Hausa, to wa lọja Abattoir, Odo Ẹran, Agege, nipinlẹ Eko.
“Owohunwa bu ẹnu atẹ lu ọwọ ipa tawọn ọlọpaa lo lati le fẹsẹ ofin tijọba ti ṣe lori bi wọn ṣe gbegi le lilo ọkada lawọn apa ibi kan nipinlẹ Eko. O waa fawọn araalu lọkan balẹ pe awọn ti gbe igbesẹ lori bi wọn yoo ṣe da ṣẹria to tọ fun wọn, ati pe ni kete ti wọn ba ti n pari eto lori iru iya ti wọn fẹẹ fi jẹ wọn, wọn yoo fi to awọn araalu leti”.
O fi kun un pe ileeṣẹ awọn ko ni i dawọ duro ninu ilakaka wọn lati mu ki ẹsẹ ofin rinlẹ, tawọn yoo si ri i daju pe awọn araalu n tẹle ofin orilẹ-ede yii.