Ọga ọlọpaa patapata, Kayọde Ẹgbẹtokun, gba awọn ọmọ Naijiria nimọran 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọga agba awọn ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, ti ṣalaye ohun ti ki i jẹ ki awọn ijọba orileede yii ṣaṣeyọri.

Ninu idanilẹkọọ to ṣe ninu ọgba Fasiti Ibadan (University of Ibadan) gẹgẹ bii oludanilẹkọọ pataki nibi ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye awọn akẹkọọ ileewe ọhun tọdun yii, eyi to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun  yii, lo ti sọ pe iwa ijẹkujẹ to ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nilẹ yii ni ko jẹ ki eto iṣejọba wa mu idagbasoke ba orileede yii to bo ṣe yẹ.

O ni iwa ibajẹ ọhun ko mọ laarin awọn oloṣelu nikan, ati pe ki iwa ibajẹ too le dopin, ti yoo si faaye silẹ fun idagbasoke orileede yii, dandan ni ki ajọṣepọ to gunmọ wa laarin awọn oṣiṣẹ eleto aabo, awọn to wa nipo ijọba pẹlu awọn araalu.

Ẹgbẹtokun, ẹni to ti kawe gboye ọmọwe, ṣalaye pe bi awọn ọmọ Naijiria ba fẹ lati fopin si iwa ibajẹ to n dènà idagbasoke ilẹ yii, ọna kan ṣoṣo ti eyi le gba waye ni ki gbogbo ọmọ orileede yii ṣe ipinnu, ki wọn si ṣiṣẹ pẹlu ootọ inu ati ifọwọsowọpọ lati mu erongba naa wa si imuṣẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Eto aabo to duro deede lo n fi ijọba lọkan balẹ lati roju raaye ṣeto ijọba rere, ijọba lo n ṣatọ́nà eto aabo to duro deede pẹlu ilana ijọba to duroore. Amọ ṣa o, ipa rere ti awọn araalu ba ko lawujọ lo n ṣokunfa eto aabo to duro deede, ati eto iṣejọba rere.

“Awọn eeyan maa n di ẹbi ìṣòro orileede yii ru ijọba nikan, wọn gbagbe pe awọn paapaa ni ipa tiwọn lati ko fun idagbasoke orileede yii, ati pe bi awọn araalu funra wọn ba ṣe ri, bẹẹ gẹlẹ nijọba wọn paapaa yoo ṣe ri.”

Ṣaaju lọga agba Fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Kayọde Adebọwale, ti sọ pe afojusun awọn lori àkòrí ti awọn mu fun idanilẹkọọ ti wọn fi sọri ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye ọdun yii ni lati tanna wo iṣoro Naijiria ati ipa to yẹ ki awọn araalu ko fun ifẹsẹrinlẹ eto aabo ati idagbasoke orileede yii.

Leave a Reply