Ọga ọlọpaa patapata lorileede yii, Muhammed Adamu, ti paṣẹ pe ki wọn mu ọkan ninu awọn ajijagbara nilẹ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, nitori gbedeke ọjọ meje to fun awọn Fulani lati ko ẹru wọn kuro niluu Igangan, nipinlẹ Ọyọ laipẹ yii.
ALAROYE gbọ pe Agbẹnusọ Buhari lori eto iroyin, Garba Sheu, lo fidi eleyii mulẹ lasiko ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ilẹẹṣẹ tẹlifiṣan BBC Hausa lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.
Ọkunrin naa ni ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa sọ foun pe oun ti paṣẹ fun Kọmiṣanna awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Ngozi Onadeko, lati fi ọwọ ofin mu Igboho, ki wọn si gbe e wa si Abuja lai fakoko ṣofo.