Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Salami Amidu Bọlaji, ti ni ko ni i saaye fun oloṣelu tabi janduku kankan lati da omi alaafia ipinlẹ Ondo ru ṣaaju ati lẹyin eto idibo gomina to fẹẹ waye lọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun ta a wa yii.
Ọga ọlọpaa ọhun ṣe ikilọ yii niluu Akurẹ, lasiko ipade alaafia kan to ṣe pẹlu awọn asaaju ẹgbẹ oṣelu to wa nipinlẹ Ondo lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
O ni ikilọ yii ṣe pataki latari ati dẹkun rogbodiyan to n waye lawọn ibi tawọn oloṣelu ti n polongo laarin bii ọsẹ diẹ sẹyin.
Ẹẹmeji ọtọọtọ lo ni oun ti ba awọn tọrọ kan ṣe iru ipade yii, ṣugbọn ti wọn ko tẹle adehun ti awọn jọ ṣe.
O waa fi asiko naa rọ gbogbo awọn oloṣelu lati tete kilọ fawọn ọmọ lẹyin wọn nitori pe gbayawu ni ilẹkun ọgba ẹwọn Olokuta si ṣilẹ fun ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o ba wọn lọwọ si jagidijgan lati asiko yii lọ.
Salami ni awọn ti ṣetan ati doju ija kọ ẹnikẹni to ba n gbiyanju ati di aṣeyọri eto idibo naa lọwọ.